ISEGUN DAJU FUN ONIGBAGBO TO NRIN NI ISOTITO
O dara lati je okunrin rere ati obinrin rere. Bibeli wipe eniyan rere fi oju rere han, a si winni, imoye ni yio maa fi la ona ise re. Nitori ti a ki yio yii nipo pada laelae. Olododo yio wa ni iranti titi aye. Ki yio beru ihin buburu, aiya re ti mu ona kan, O gbekele Oluwa. Aiya re ti mule ki yio beru, titi yio fi ri ife re lori awon ota re. O ti fun ka o ti fi fun awon talaka, ododo re duro laelae, ola ni a o fi gbe iwo re ga (Orin Dafidi 112:5-9)
EKO
Enikeni ti o ba fi otito tele Olorun, ogun kan tabi iji aye kan ko ni bori re. Ogun lee le, sugbon Olorun yio mu ki awon ti o telee ni otito ki won gunle si ebute ayo. Ni aarin inunibini omokunrin ati omobinrin Olorun yio yayo isegun, sugbon awon eniyan buburu ti o nni olododo lara, yio yo bi igba ti ori abela ba foju kan ina, won yio dara won lebi, ayafi bi won ba ronupiwada.
ADURA
Mo gbadura ki Olorun je ki okan mi duro sinsin, ki o ma se O nitori iji igbogun. Ki Jesu Kristi, yio si gba awon eniyan mimo sinu ijoba re. Jowo ka mi ye lati le gba ade ogo ti kii baje, ki o si fi ewa ati owo se eso simi lara. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
