MAA SE AKIYESI IMULO ORO ENU RE
Bibeli je iwe-atoni/atoka ti Olorun fowo si fun gbogbo Kristeni lati maa ko eko ninu re, ki a si maa telee. Bibeli so wipe, ‘se aapon lati fi ara re han niwaju Olorun ni eni ti o yege, osise ti ko ni lati tiju, ti o npin oro otito bi o ti ye. Sugbon ya kuro ninu oro asan, nitori ti won o maa lo siwaju ninu aiwa-bi Olorun. (2 Timotiu 2:15-16)
EKO
Kristeni je igbe aye esin ti o ye ki enikeni ti o baa nsin in ki o see tokantokan. Enikeni ti o ba je Kristeni ni lati maa ka bibeli re, iru eni bee nilati maa gbadura, ki o si muu wa si amulo ohun ti o ba ko ninu re. O si se Pataki ki Kristeni ni oro ti o sanfani, ati ninu ise. Omo Olorun ko ye ki o soro efe ti yio kin Satani lehin ati ise ibi re. Oro enu re ni lati kun fun ore-ofe ti yi o yin Olorun logo ni gbogbo akoko. Ni afikun, bi o ti je ojuse Kristeni lati maa waasu ihinrere, pelu awon eniyan, a ko gbudo wonu ariyanjiyan ti yio fa iyan jija, ti ko nitumo ti nse asan, ati oniruru aiwa bi Olorun. Orun yio patewo fun Kristeni ti o ba tele ilana bibeli ti o si ni aya pipe (funfun).
ADURA
Olorun Olufe, se mi ni Kristeni ti o un huwa bi bibeli ti wi, se mi ni olukeko oro re, ki emi si mu eko ero re lo ninu aye mi. Je ki oro mi ati ise mi kun fun ore-ofe ti yio yin oruko re logo. Dari mi ki o si ko mi lati huwa bo ti to ki emi lee je apere iyin fun oruko mimo re. Jowo je ki Emi Mimo re wo mi ni agbara lati le huwa bi Kristeni olotito, ti yio je eni itewogba lodo re ni orun rere. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin
