GEGE BI ONIGBAGBO OO RI OJURERE GBA
Omo Olorun ni lati duro ninu igbekele Olorun, ki o duro sin sin pelu ijewo igbagbo ninu Jesu Kristi. Bibeli wipe ‘nitori pe Olorun, ko fun wa ni emi iberu, bi ko se ti agbara, ati ti ife ati ti okan ti o ye kooro. Nitori naa ma se tiju eri Oluwa wa, tabi emi onde re, sugbon ki iwo ki o se alabaapin ninu iponju ihinrere gege bi agbara Olorun. (2 Timotiu 1:7-8)
EKO
Awa Kristeni ni a se ni ire ju ninu awon eniyan ni ile aye, o si ye ki a duro ninu igbagbo wa nipa jijewo ninu Jesu Kristi. Awa Kristeni je eni ti yio lo si orun, Jesu Kristi yio je agbejoro fun wa nikehin ni ojo idajo, niwon igba ti won ti jewo Jesu Kristi ni Oluwa ati Olugbala won. Kristi yio bebe fun awon ti ntele (awon ti o bagbaa gbo) ki Olorun dari ese won ji won, nitori eje re ti o yonda nitori won. Niwon igbati Kristi je alaidese, sugbon o ku fun awon elese, Olorun yio gbo ebe re, a o si da awon Kristeni lare. Nitori naa o je ohun iyebiye fun enikeni lati je Kristeni. Enikeni ti ko ba ti gba Jesu Kristi ni Oluwa ati Olugbala re, ki o se bee kiakia lai fi akoko sofo. Nitori Jesu Kristi nikan ni agbejero tooto ti o lee duro niwaju idajo. Ologbon nipa jijewo Jesu Kristi gegebi Oluwa ati Olugbala, nitori Orun rere yio je ibugbe re laelae.
ADURA
Aaa eje Jesu we mi, Aaa eje Jesu ti a ta sile fun mi, iru etutu ti o gba aye mi la. Beeni eje naa ni isegun mi. O seun Jesu Kristi fun ise rere ti o ti pari lori igi agbelebu fun mi. O ku lati gba okan mi la kuro ninu idalebi ati idajo orun ina apaadi. Nitorina, mo yonda gbogbo aye mi fun o lati oni lo, mo jewo re Jesu Kristi bi Oluwa aye mi, mo si jewo re bi Olugbala mi. Jowo we ese mi nu, ki o si gba mi gegebi omo re ti yio jogun ijoba ainipekun re. Oseun Jesu Kristi fun ore-ofe igbala re. Amin
