WIWA NINU ESE SIBE SI O L’EWU
Iduro Israeli ninu ese won fa ibinu Olorun, o wa seleri lati fi iya ti o lagbara je won. Olorun so fun Isikieli pe, Omo eniyan, nigba ti ile naa ba se si mi nipa irekoja buburu nigba naa ni emi o nawo mi lee, emi o si se opa ounje inu re, emi o si ran iyan sii, emi o si ke eniyan ati eranko kuro ninu re. Bi awon okunrin meta wonyii, Noa, Danieli ati Jobu tile wa ninu re, kiki emi ara won ni won o fi ododo won gba la, ni Oluwa Olorun wi. Bi mo baje ki eranko buburu koja laarin ile naa, ti won si baaje, tobee ti o di ahoro, ti enikan ko le laa ja nitori awon eranko naa. Bi awon okunrin meta wonyi tile wa ninu re, Oluwa Olorun wipe, bi mo ti wa, won ki yio gba omokunrin ati omobinrin la, awon nikan ni a o gba la, sugbon ile naa yio di ahoro. (Isikieli 14:13-16).
EKO
Olorun ko lee gba ese laaye, enikeni ti o ba duro ninu ese yi o jiya. Enikeni ti o ba ko lati ronupiwada, yio ku sinu ese, ko ni ri Olorun ni orun. Iru eni bee yio doju ko ewu ina orun apadi. Okan ti o ba se oun o ku (Isikiel 18:20). Enikeni ti o ba fi irele jewo ese re ti o si ronupiwada, yio ri idariji gba. A lee ri idariji ese gba ninu oruko Jesu Kristi. Jesu Kristi yio je agbejoro fun elese ti o ba bebe fun idariji ese pelu oruko re. Olugbala yio sipe fun un lodo Olorun fun idariji ese ati imupada sipo. Nitori naa, enikeni ti o ba fe jogun Olorun ni lati wa si ese Kristi, ki o jewo re ni Oluwa.
ADURA
Jesu Olufe, mo mo pe, enikeni ko lee jogun ijoba Olorun lai je pe o koko gba o ni Kristi, ki o jewo re ni Oluwa re. Nitori naa, mo kede re ni Oluwa mi looni. Mo jewo ese mi, mo si ko won sile. Lati akoko yi lo, mo se ipinu ni otito lati maa tele o, emi o fi gbogbo okan mi sin o, ki emi lee jogun ijoba Olorun. Mu ese mi duro ni enu ilekun re. Si ka mi ye lati je alabapin ninu alafia ayeraye ati ayo ni orun. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin
