MAA SE ASARO NINU ORO OLORUN
Oro Olorun duro, o si pe, a nilati tumo re ki o baa le se ojuse re ninu aye onigbagbo. Nitori naa, Kristeni ni lati rii wipe won ni ibasepo ati idapo pelu awon iranse ajihinrere ti won duro ninu otito Bibeli. A ko lee yo kuro tabi ki a fi kun bibeli ti a ba ntumo re. O ni lati rorun, otito, se ojuse re lati yin Olorun logo, ki awon eniyan si di eni ibukun. A koo wipe bi enikeni ba nkoni ni eko miran, ti ko si gba oro ti o ye kooro, ani oro Jesu Kristi Oluwa wa, ati eko gege bi iwa bi Olorun. O gberaga, ko mo nnkan kan, bi ko se ife iyan jija ati ija-oro ninu eyi ti ilara, iya, oro buburu ati iro buburu ti nwa oro ayipo awon eniyan olokan eeri ti ko si otito ninu won, ti won sebi ona si ere ni iwa bi Olorun yera lodo iru awon won-on-ni (1 Timotiu 6:3-5)
EKO
Ojulowo Kristeni ni lati maa yayo otito inu bibeli. A nreti won lati ma tumo bibeli lai fi kan pe omiran. Ogidi Kristeni ni lati ni imo, ki o si maa yayo Olorun nipa ife, iwa omoluwabi, iwa-mimo. Eyi ti o se Pataki julo, Kristeni tooto ni lati mo bi a se le yan adari emi ti o ni iwa bi Olorun. Ko si je ojulowo Kristeni ti yio joko labe Oludari ti okan irele, ti o si unbomi rin oro bibeli. Kristeni ko ye ki o tele awujo lati se ohun ti won ban se. O ye ki o keko ninu bibeli nigba gbogbo, ki o le rii daju pe ohun ti oun nse, o dara niwaju Olorun. Ni akotan, Kristeni daradara ni lati kun fun adura, ki o kun fun Emi Mimo, ki o le ni oye pipe bibeli, ki o ba lee te Olorun lorun. Jehofa yio b’ola fun kristeni olododo ninu aye yi ati ni orun pelu.
ADURA
Olorun Olufe, jowo se mi ni Kristeni ti yio sin o tokantokan. Fun mi ni ore ofe lati yayo ninu awon ohun ti yio mu inu re dun. Mase je ki emi tele awujo lati se ibi, je ki emi gbe igbe aye iwa mimo, ti yio gba ibukun re. je ki emi kiyesara si gbogbo eko ti mo ba gba, ro mi ni agbara emi mimo, ki emi lee maa yayo ojulowo otito re. Je ki irin mi pelu re je mimo, ki emi lee jogun ijoba re ayeraye,. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin
