OLORUN KUN FUN AANU FUN AWON TIRE
Olorun fi ife baba han si awon Israeli ti a ko sile nigba ti won ti jiya iwa aigboran won. Eledaa yio din in ku, eru wuwo Israeli mu won wa sile lati igbekun ti won lo. Olorun so fun Isikieli nipa Israeli ‘Nitori naa wi pe, bayii ni Oluwa Olorun wi, bi mo tile ti ta won nu rere laarin awon keferi, bi mo si ti tu won ka laarin ile pupo, sibe emi o je ibi mimo kekere fun won ni ile ti won o de. Nitori naa wipe, bayi ni Oluwa Olorun wi pe, emi tile ko yin kuro lodo awon orile ede, emi o si ko yin jo lati ile ti a ti tu yin ka si, emi o si fun yin ni ile Israeli. Won o si wa sibe, won o si mu gbogbo ohun irira re ati gbogbo ohun eeri re kuro nibe. Emi o si fun won ni okan kan, emi o si fi emi titun sinu yin, emi o si mu okan okuta kuro lara won, emi o si fun won ni okan eran. (Isikieli 11:16-19)
EKO
Olorun kun fun ore-ofe ati aanu, ko ni ta elese nu laelae, sugbon yio dawon pada sinu otito ife re. Bi ese ti eniyan da se tobi to, Jehofa seto ona irapada fun wa. Olorun loye pe eniyan ni wa, ti a da lati inu erupe ile, a jina si pipe, nitori naa, yio ba wa sise, titi ti yio fi ra wa pada ni pipe. Jehofa yio dari ese wa ji wa, yio si mu wa pada wa sinu ife re. Lati lee se eyi, o ran omo re kansoso, Jesu Kristi wa sile aye, lati gba araye la. Kristi yio ku fun ese omo eniyan, yio si mu wa laja pelu eledaa wa. Kristi se aseyori wonyi, nitori naa omo eniyan ni lati gbaa gbo, ki won le di eni igbala. Enikeni ti o ba nwa irapada kuro ninu ese ni lati jewo Jesu Kristi ni omo Olorun nikan soso, ki o si gbaa ni Oluwa ati Olugbala re.
ADURA
Olorun Olufe mo mo pe elese ti o unrun ni mi, emi ko si ye fun ohunkohun lodo re. Sugbon mo wa pelu irele looni fun idariji ese mi. Jowo fi oriji mi ninu gbogbo ese mi, ki o si we mi mo ninu aisotito mi, fun mi ni irapada ati imupada nipa igbagbo mi ninu Omo re, Jesu Kristi. Mo jewo igbagbo mi ninu Jesu Kristi, mo sigbaa ni Oluwa ati Olugbala mi. Jowo ko oruko mi sinu iwe iye, si ka mi ye lati je alabapin ninu ijoba ayeraye re. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere, Amin.
