AWON IRANSE OLORUN GBODO SE OLOTITO
Oro iyanju Aposteli Paulu si awon ara Tesalonika, o wipe nitori oro iyanju wa kii se ti etan, tabi ti iwa aimo, tabi ninu arekereke. Sugbon bi a ti ka wa ye lati odo Olorun wa, bi eni ti a fi ihinrere le lowo, kii se bi eniti nwu eniyan bi ko se Olorun, ti n dan okan wa wo. Nitori awa ko lo oro iponni nigba kan ri gege bi eyin ti mo, tabi iboju ojukokoro, Olorun ni elerii. Be ni awa ko wa ogo lodo eniyan, tabi lodo yin, tabi lodo awon elomiran, nigba ti away iba fe ola lori, yin bi awon aposteli Kristi (1 Tesalonika 2:3-6).
EKO
Awon iranse Olorun ko gbodo je eni ti yio maa lepa lati te eniyan lorun. Oye ki won maa waasu bi Emi Mimo ba se ndari won, ki won si maa se itoka si bibeli ninu iwaasu won. Olorun kii ni inu didun si awon ti o ba kuna. Awon iranse Olorun ko gbodo maa se ilepa oro aye ju ihinrere otito, ki won mase je onimo tara eni nikan, ki won di igbagbo won mu ni akoko inunibini ati idojuko. Jehofa ti seto ni kikun, anfani fun awon iranse re ti o ba fori tii de opin. Yio bukun awon iranse re, yi o si fi owo see looso ni orun.
ADURA
Olorun Olufe se mini olotito iranse niwaju re. Ran mi lowo lati duro deede nigbogbo igba. Je ki emi le waasu ogidi ihinrere. Se mi ni olotito, ki emi maa so eso sinu ijoba re. Fi kun agbara mi ni akoko inunibinu, ki emi si duro ninu igbagbo titi di opin. Jowo fi ororo ayo ati idunu fun mi, ki emi tesiwaju lati maa waasu ihinrere kakiri gbogbo aye ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
