OLORUN TABI ORISA?
Awa Kristeni kii sin Olorun aimo, sugbon awa nsin Olorun ti a mo, ti o wa ni orun, o si njoba lori aye. Bibeli salaye pe ‘Nitori kini awon Keferi yio se wi pe nibo ni Olorun won wa, nisisinyi? Sugbon Olorun wa nbe ni orun o nse ohunkohun ti o wu u. Fadaka ati wura ni ere won, ise owo eniyan. Won ni enu, sugbon won ko soro, won ni oju, sugbon wonko riran, won ni eti sugbon won ko gboran, won ni imu sugbon won ko gboorun, won ni owo sugbon won ko loo, won ni ese sugbon won ko rin, bee ni won ko soro lati ofun won jade. Awon ti n se won dabi won, bee ni olukuluku eni ti o gbekele won.(Orin Dafidi 115: 2 – 8).
EKO
Olorun korira iborisa, o si je iwa ailogbon ki enikeni maa sin orisa. Kini anfani ti eniyan lee ri ninu iborisa. Ko si rara, o dara ki awon eniyan lati ma sin Olorun alaye, dipo orisa ti ko le soro. Olorun alaye nikan ni o da gbogbo aye, ti o si njoba lawujo omo eniyan, gbigbeke lee yio mu ere pupo wa. Eledaa yio bukun gbogbo awon ti o ba gbeke lee, sugbon yio ko awon aborisa yio si fiya je won, ayafi bi won ba ronupiwada.
ADURA
Olorun Olufe, jowo je ki emi le maa sin o ni gbogbo igba pelu okan kan, ki emi si dari iyin ati adura mi si yin nigba gbogbo. Je ki nmu iduro mi pelu re se deede ni gbogbo ojo aye mi. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
