DI ORO OLORUN MU SINSIN
Paulu salaye Pataki oro Olorun (Akosile ati Iminsi) o wipe bi ihinrere wa ko ti wa sodo yin ni Oro nikan, sugbon ni agbara pelu, ati ninu Emi Mimo, ati ni opolopo igbekele, bi eyin ti mo iru eniyan ti awa je laarin yin nitori yin. (I Tesalonika 1:5)
EKO
Ise meji Pataki ni oro Olorun nse, o nfun ni ni itumo ijinle ogbon (eyi ti a npe ni LOGOSI – Oro akosile) ati agbara Emi (ti a npe ni RHEMA – Oro Nipa Iminsi Emimimo). Mejeji ni o ye fun enikeni ti o ba fe se aseyori ni ile aye; ati lati wo ijoba Olorun. Niwon bi oro Olorun se je Pataki, gbogbo Kristeni ni lati loye re dara dara. Bi Kristeni ba se npo si ni kikeko oro Olorun, bee naa ni igbe aye re yio maa dara sii.
ADURA
Olorun Olufe, jowo ran mi lowo lati maa keko bibeli (eyi ti o je oro re) ni gbogbo igba. Fun mi ni ore-ofe lati duro ninu oro re, ki emi le ni imo ati ogbon, ti emi o fi gbe igbe aye aseyori ni aye, ki won si ka mi ye lati wo ijoba ayeraye re. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
