ILANA JESU LATI GBA ARAYE
Jesu juwe ara re bi Kristi, Mesaya araye. O si fi han ipinu re lati ji dide ninu ipo oku, ki o si gba araye la, Jesu wipe ’Ati emi bi a ba gbe mi soke, kuro ni aye, emi o gb a gbogbo eniyan sodo ara mi.
(Johanu 12:32)
EKO
Jesu ni Kristi, oun si ni Oluwa. O ti se ilana bi yi o se gba araye la, ero Jesu Kristi ni lati ku ki o ji dide, ki o ba le gba araye la, o se ohun gbogbo gege bi ilana. O fara da inunibini awon ota, o si ku ni ori igi agbelebu, a sin si iboji oku, sugbon o ji dide si aye lehin ojo keta, lehin ajinde re o ni ajose pelu awon omo ehin re, o si fi dawon loju pe, oun o ji won dide kuro ninu ipo oku. Olugbala so wipe anfani yi o wa fun awon ti o ba gba a gbo lehin igba naa, gbogbo eniyan ti o ba Gbagbo ninu Jesu Kristi ni a o ji dide kuro ninu iku si iye, a o si gba won si orun rere ni ojo ikehin. O seni ni aanu pe, awon alaigbagbo yi o ni ipin won ninu ina orun apadi, ibi oro titi lae, enikeni ti o ba fe lo si orun rere ni lati gba Jesu Kristi ni Oluwa ati olugbala re.
ADURA
Jesu Kristi olufe, emi yi o dekun fifi akoko mi sofo ninu aigbagbo. Emi ko fe fi orun ina apadi sere mo, nitori naa mo jewo, mo si ko ese mi sile, mo jewo Jesu Kristi ni Oluwa ati olugbala mi, mo gbagbo wipe o ti ku fun ese mi, o si ji dide lati fun mi ni iye ayeraye. Niwon ti mo ti di omo re, mo gbagbo pe o ji mi dide ninu iku si iye, emi o si lo si orun, mo ye fun orun rere beeni mo unlo si orun, itiju fun satani, ogo fun Olorun. Amin.
