FI AYE RE FUN JESU
Dafidi salaye awon anfani ti o ti ri gba lati owo Olorun ni igba ti o ti jowo aye re fun un. Dafidi wipe’Ni diduro emi duro de Oluwa, o si deti si mi, o si gbohun ekun mi, o si mu mi goke pelu lati inu iho iparun jade wa, lati inu erupe ere, o si fi ese mi ka ori apata, o si fi isise mi lele. O si fi orin titun si mi lenu ani orin iyin si Oluwa wa, opo eniyan ni yoo rii ti yoo si beru, ti yoo si gbekele Olorun, ibukun ni fun okunrin naa ti o fi Oluwa se igbekele re, ti ko si ka onirera si, tabi iru awon ti nya si ona eke.
(Orin Dafidi 40:1-4)
EKO
Enikeni ti o ba fi aye re fun Olorun yi o gbadun anfani pupo, iru eni bee yi o ri iranlowo Olorun gba ni akoko, yi o si ri ibukun gba. A ni lati fi kun igbagbo wa ninu Oluwa ni akoko ipenija wa nitori akoko isoro maa unwa pelu inilara, enikeni ti o ba fi oro re le Olorun lowo ni akoko ipenija yi o rerin laipe. Olorun untoju awon omo re, ko si ni je ki oju ti won ninu isoro, Jehofa yi o gbeja fun awon eniyan ti o ba gbeke lee, yi o je ki won ko orin eri.
ADURA
Olorun olufe, jowo ko mi lati gbeke le o ni akoko isoro, je ki emi lee ke pe o ni akoko idanwo, si fun mi ni ore-ofe lati sope fun o lehin ti mob a ni aseyori. Je ki enu mi kun fun orin iyin, si je ki emi le fi ayo jeri didara re ni gbogbo ojo aye mi. ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
