ASIWERE NI KOSI OLORUN
Bibeli so ni pato wipe ASIWERE ni enikeni ti o ba so wipe Olorun ko si. Bi ko ba si Olorun, ta ni o se awon ohun ti o rewa gbogbo ti a nri loni? Bi ko ba si Olorun tani iba di ojo igba ati akoko ni pipeye bo se wa, bi ko ba si Olorun, tani iba ti da eniyan ni pipe ba a se ri looni. Olorun wa, ajulo re yi o wa titi aye. Bibeli kilo fun awon ti o so wipe ko si Olorun, ki won ki o ronupiwada kuro ninu ese won, o wipe ‘Asiwere wi ni okan re pe Olorun ko si, won baje won sin se irira ese, ko si eni ti o nse rere, Olorun boju wo ile lati orun wa sara awon omo eniyan, lati wo bi enikan wa ti oye ye, ti o si nwa Olorun. Gbogbo won ni o si pada seyin, won si di eleeri patapata, ko si eni ti nse rere ko si enikan. (Orin Dafidi 53:1-3) bibeli wipe ‘Sugbon gege bii lile ati aironupiwada okan re ni iwo nfi ibinu pamo fun ara re de ojo ibinu ati ti ifihan idajo ododo Olorun, eni ti yoo san fun olukuluku gege bi ise re.
(Romu 2:5-6)
EKO
Ologbon ni awon ti o gbagbo pe Olorun wa, alaigbagbo tabi asiwere ni awon ti o so wipe Olorun ko si. Bibeli pe awon ti ko gba wipe Olorun wa ni asiwere. (Orin Dafidi 53:1-3) Olorun wa a ko le se wiwa re, bi a ko tile ri Olorun a lee ri ise owo re, gege bi nnkan ti a ngbo pe ohun gbogbo dede wa, Olorun ni o da ohun gbogbo. Aye ko da eniyan ni pipe bi a se wa daradara yi, Olorun da eniyan ni awo pipe, eniyan ni eti meji ni ori, eniyan ni ese meji ki o le duro dara dara, oni oju meji pelu ipenpeju lati le eera ati esinsin kuro. Eniyan ni enu lati fi je ounje, o ni onamisu lati ya ounje ti o je, ta lo ni Olorun kosi? Iru eni bee ko gbon. A ba ti da ofurufu ni orisi awo, tani iba mu ki igi ni awo eweko ti ko ni ba oju wa je, tani iba da yiyo oorun ati wiwo oorun ti won ki tako akoko won, tani iba da igba ati akoko ti won unyipo ni ododun, igba lai kuna akoko won. A ko nilo ikeko roketi lati mo wipe nkan kan nbe lehin iseda, nkan kan wa lehin iseda ohun ti a da ni Olorun, gbogbo eniyan nilati bowo fun un. Ewa aye yi ko see fi we ewa ti orun ti Olorun unpese fun awon eniyan mimo re, enikeni ti o ba fe je anfani Olorun ni lati pinu lati lo si orun rere. Jesu Kristi ni omo Olorun, oun nikan ni ona ti o lo si orun, gbogbo eniyan ni lati gbagbo.
ADURA
Olorun olufe, mo mo pe iwa were ni lati maa jiyan pe Olorun ko si mo, wiwa re o si wa ju ohunkohun lo. Mo dupe fun aye ti o rewa ti o da, mo loye pe opolopo ise ewa ni o wa lorun, mo si fe rii. Jowo ka mi ye lati le wo orun rere ni ojo ikehin, mo gbagbo ninu omo re Jesu Kristi mo si gba o ni Oluwa ati olugbala mi, mo mo wipe a o gba mi si ijoba re nipa igbagbo ninu omo re Jesu Kristi. Amin.
