GBIN SIPA TI ORUN; KO SI N SE SI AYE YI RARA
Jesu Kristi ro awon omo ehin re ki won to isura won jo si orun, ki won ba le jere ailopin lati odo Olorun. Kristi so itan ti lati fi gbe oro re niidi ‘ ile okunrin kan oloro so opolopo. O si ro ninu ara re wi pe, emi oti se, nitori ti emi ko ni ibi ti emi o gbe ko eso mi jo si. o wi pe, eyi ni emi o se, emi o wo aka mi pale, emi o si ko eyi ti o tobi, nibe ni emi o gbe to gbogbo eso ati oro mi jo si. Emi o wi fun okan mi pe, okan, iwo ni oro pupo ti a to jo fun opo odun, sinmi maa je, maa mu, maa yo. Sugbon Olorun wi fun un pe, iwo asiwere, ni oru yii ni a o beere emi re lowo re, nje ti ta ni nnkan won-on-ni yoo ha se, ti iwo ti pese sile? Bee ni eni ti o to isura jo fun ara re, ti ko si ni oro lodo Olorun. (LUKU12:16-21).
EKO
Enikeni ti o ba nro ti aye, ti ko si to isura kan soso si orun yi o jogun ofo ni ojo idajo Olorun ni ikehin. Oro aye fun igba die ni won yi o wa fun igba die won a si pare. Oloro eni le ku bi abosi ni ola. Bi o tile ku pelu fifi opolopo oro sile fun awon omo re, won le ma le toju oro naa. Sugbon ohunkohun ti eniyan ba gbin si orun ko ni pare, sugbon yi o wa titi aye. Ohunkohun ti a le pe ni isura orun ni lati ma pe akiyesi eniyan si Olorun ki o si ma fi ogo fun. Ti a ba ni ki a wo awon ojuse ti o ye fun orun, onigbagbo ti o nse itoju ti o si ngbadura fun awon elomiran yi o gba ebun lati orun, bakan naa Kristieni ti o ba njere okan yi o ri ebun gba lati orun. Nitori naa, gbogbo omo Olorun ni a pe lati je asoju Kristi ni aye, ki a si sa gbogbo ipa wa ni ijere okan si ijoba Olorun, ki won ba le gba aidibaje oro ti ko niye, gegebi anfani ti orun.
ADURA
Olorun olufe, jowo ran mi lowo lati le maa to isura mi jo si orun nibi ti ko si idibaje. Mase je ki nko si panpe ilepa afe aye bi ohun ti o je ilepa mi nikan. Ro mi ni agbara, kinle lo owo mi, dukia mi, ife mi si ijoba re. se mi ni asoju re tooto kinle ni ipin ninu ijoba aidibaje re, je ki emi mimo re se amona mi, kinle ni aseyori ninu ohun gbogbo. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
