IGBORAN PATAPATA SE PATAKI FUN IBUKUN OLORUN
Awon Isreali se aigboran si Olorun ti o ni ki won pa gbogbo eya Kenani run ni ile Kenani ti o ti seleri fun won. Isreali da awon olugbe ile na die si, won si ni ibare pelu won. Won sin sin orisa Kenani ti o je eewo won (a ri wipe awon olugbe yi wa di ota fun won) eyi ti o wa buru ju, Isreali wa pinya yeleyele, won so isokan won nu, eyi ti omu ki ijoba apapo di alailagbara. Bakan naa, ibinu Olorun ruu si won. Bibeli so wipe ‘Awon omo Isreali si se buburu ni waju Oluwa, won sinsin Baalimu. Won si ko Oluwa Olorun awon baba won sile, ti o mu won jade lati ile Egibiti wa, won si nto Olorun miran leyin, ninu orisa awon eniyan ti o yi won ka kiri, won si nfi ori won bale fun won, won si bi Oluwa ninu. (AWON ONIDAJO 2:12-13).
EKO
Omo Olorun ni lati gboran si ase Olorun ki won le je anfani re. A ko ni lati se abo igboran pelu Olorun. Bi o ti je ti Olorun ni ko si aye fun abo igboran. Yala ki aje olugboran tabi alaigboran itan fi ye wa wipe ni aye bibeli, gbogbo awon ti ose abo igboran gba ijiya to to. Fun apere, awon Isreali ko lati pa gbogbo ara Kenani run patapata won si jiya re. bakan naa, oba Saulu ko lati pa gbogbo ara Amaleki run, o gba idajo ti o buru (samueli kini 15) Olorun kan naa ti ko yipada mu opa idajo re sori awon ti ko ba pa ase re mo ni pipe. Nitori na awa (onigbagbo) nilati gboran si ase Olorun, ki a si sa gbogbo ipa wa lati tee lorun ni gbogboigba, bi kotile tewa lorun. Jehofa yi o san wa lesan ti o ba gboran si ase re, sugbon ko ni rerin si onigbagbo ti o ba fe gbon ju Olorun lo pelu ‘abo igboran’.
ADURA
Oluwa olufe, ran mi lowo ki nle gboran ki nle di alabukun ni ile alaaye. Ma se je ki ri mi mu pelu abo igboran ti o tumo si aigboran. Mo mo pe aigboran nyori si ijiya nla, nko si fe nipin ninu re. nitori na, e ro mi ni agbara nipase emi mimo lati le rin lona re, gboran si ase re kin ba le se rere. Gbin eru re simi lokan, dari mi ni gbogbo ona mi, kinle gbe igbe asegun ni ile alaaye ati pelu kinle jogun ijoba ayeraye. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
