DURO PELU OLORUN, OO SI GBA ERE RE
Josua, iranse Olorun wa ronu iriri re pelu Olorun lehin ti o ti lo odun mewa le ni ogorun odun, o si ti ri ijolotito larin awon Isreali. Josua ti ri bi Olorun se mu awon. Isreali jade kuro ni ile Egibiti wa si ile-ileri lona iyanu. Adari Isreali gba won niyanju lati maa pa ofin Olorun mo ki won ba le ma je anfani re. josua wipe ‘Nitorina e mura gidigidi lati toju ati lati se ohun gbogbo ti a ko sinu iwe ofin Mose, ki eyin ki o ma se yipada kuro ninu re si owo otun tabi si owo osi ki eyin ki omma se wa saarin awon orile-ede wonyi, awon wonyi ti o ku pelu yin, ki eyin mase da oruko orisa won, bee ni ki e ma se fi won bura, e ma se sin won, bee ni ki e ma se terbia fun won. Sugbon ki eyin faramo Oluwa Olorun yin, gegebi eyin tin se titi di oni. Nitori ti Oluwa ti le awon orile-ede nla ati alagbara kuro niwaju yin, sugbon bi o se ti yin ni, ko si okunrin kan ti o ti duro niwaju yin titi di oni. Okunrin kan ninu yin yoo le egberun, nitoripe Oluwa Olorun yin, oun ni eni ti nja fun yin, gege bi o ti so fun yin. (JOSUA 23:6-10) Josua salaye fun awon omo Isreali abajade iya ti won yi o je bi won ba se aigboran si ofin Olorun. O wipe ‘ yoo si se gege bi ohun rere gbogbo ti se fun yin, ti Oluwa Olorun ti se fun yin, beeni Oluwa yoo mu ibi gbogbo ba yin, titi yio fi pa yin run kuro ni ile daradara yi ti Oluwa Olorun yin ti fi fun yin. Nigba ti eyin ba re majemu Oluwa Olorun yin koja, ti o pa lase fun yin ti e ba si lo ti e ba sin orisa tie yin ba te ori yin ba fun won, nigba naa ni ibinu Oluwa yoo ruu si yin,eyin yio si segbe Kankan kuro ni ile daradara ti o ti fi fun yin.
(JOSUA 23:15-16).
EKO
Oju Oluwa koni kuro lara awon ti o ba nsin dede. A ko ni ko awon ti o ba pa ofin re mo, sugbon won di eni ibukun. Ko see se ki Olorun fi awon omo re sile ti o nsise re, yi o duro tiwon, yi o si sanu won. Jehofa yi o pese fun awon eniyan tire laelae, yi o tan aini won, yi o siri wipe won ni isegun lori igbenija won gbogbo. Bakan naa awon ti o ba ko lati sise fun Olorun ati awon apehinda won a jiya lowo ota won. Olorun ko ni ki apehinda lehin, nitori ko ni pologo iwa buburu. Apehinda yonda ara re fun idaloro ota, won ko sini ri ere gba lodo Olorun. Yala yi o se wa ni anfani ki a gba Olorun gbo ki a si ma sin in, enikeni ti o ba ni ohun feran Olorun, ni lati jewo Jesu Kristi ni Oluwa ati olugbala re. bakan naa, apehinda(ti o ti pehinda si Olorun) ki o ronu piwada, ati ni irele ki o pada sodo Olorun lati gba igbala, ore-ofe, abo, ayo, Alafia ati awon ohun didara miran lodo re. niwon igbati Olorun wa laaye, enikeni ti o ba gbagbo ti o si fi otito sin in, ki yio gba ere itiju, sugbon yi o bori ni gbogbo ona funijeri si didara Oluwa.
ADURA
Olorun olufe, mo mo pe o feran awon ti o ni ajosepo daradara pelu re, o si san won lesan to dara, mo beere ki o fun mi ni ore-ofe, ki nle je olotito si o ninu ise mi ni gbogbo akoko. ma se je kin gbojege igbagbo mi, sugbon je kin le di ijeri igbagbo mi mu gege bi Kristieni tooto. Jowo mu ese mi duro ni enu ona re ki nba le ri iranlowo re gba ninu aye, ati ki emi ye fun anfani ijoba re ayeraye. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
