AGBARA ADURA
Paulu be awon Kristeni elegbe re ki won maa gbadura fun oun ki o ba le ni okun fun wiwaasu ihinrere. Paulu bebe ‘E maa duro sinsin ninu adura gbigba, ki e si maa sora ninu re pelu idupe. Juu gbogbo re, e maa gbadura fun wa pelu, ki Olorun le si ilekun fun wa fun oro naa, lati maa so ohun ijinle Kristi, nitori eyii ti mo se wa ninu ide pelu. Ki emi ki o le fi han, gege bi o ti to fun mi lati maa so. (Kolose 4:2-4)
EKO
Adura je ohun elo to dara lati gba isegun. Onigbagbo ni lati maa gbadura nigba gbogbo ki won le maa kun fun ayo ati ibori. Adura wa ki o mase duro lori ohun amulo fun ara wa nikan, sugbon ki o je ojuse wa lati maa gbadura fun agbara Olorun ki a le sin ni otito. A nilo okun Olorun lati le maa sin in. Ti a ba gbadura, Emi Mimo yio kun inu wa, ru agbara wa soke lati duro fun Olorun. Gbigba adura yio fi okun kun igbagbo wa, lati fi igboya waasu ihinrere. A o le dojuko idanwo, a o si ni agbara lati se bo ti to. Ni afikun, a nilo adura fun wiwaasu ihinrere, ki elese le ni idalebi, ki o si gba Jesu Kristi Oluwa sinu aye re.
ADURA
Olorun Olufe, jowo ko mi bi a se ngbadura. Ran mi lowo lati le gbadura ti yio se itewogba loju re. Je ki adura mi mu esi rere jade. Ran mi lowo lati maa gbadura ni ojojumo fun agbara ati okun ninu igbagbo. Je ki adura mi gbe mi ro, ati igbe ara ro fun awon arakunrin. Si je ki adura ran mi lowo lati je ajere okan sinu ijoba re. Je ki emi ni agbara, kin le waasu ihinrere ti ko see ko sile, ki emi si je ajere okan sinu ijoba re. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere Amin.
