AWON ONIGBAGBO YIO GBA EERE
Olorun pari idajo re lori Judah ati Israeli lehin ti o ti fun won ni opolopo akoko lati ronupiwada. Pelu opolopo ikilo awon omo Olorun ntesiwaju ninu ese won, nitori naa Eledaa se idajo re lorin won, o wipe e saa yipada, olukuluku kuro ni ona buburu re, ati kuro ni ise buburu yin, eyin o si gbe ile ti Oluwa ti fi fun yin, ati fun awon baba yin lae ati laelae. Ki e ma si to Olorun miiran leyin lati maa sin won, ati lati maa foribale fun won, ki e ma si se fi ise owo yin mu mi binu, emi ki yio si se yin ni ibi. Sugbon eyin ko gbo temi ni Oluwa wi, ki eyin le fi ise owo yin mu mi binu si ibi ara yin. Nitori naa, bayii ni Oluwa awon omo-ogun wi, nitori tieyin ko lati gbo oro mi. Sa woo, emi o ranse, emi o si mu gbogbo idile orile ede ariwa wa, ni Oluwa wi, emi o si ranse si Nebukadnessari Oba Bebeli, iranse mi, emi o si mu won wa si ile yii, ati olugbe re ati si gbogbo awon orile-ede yikaakiri, emi o si pa won patapata, emi o so won di iyanu ati iyosuti si ati ahoro ainipekun (Jeremiah 25:5-9)
EKO
Aanu Olorun ni odiwon, Eledaa ni iwon opin fun elese ti o ba ko lati ronupiwada. Bi elese ba ntesiwaju ninu ese, yio doju ko ijiya ayeraye ni orun ina apadi. Nitori naa, ki gbogbo eniyan gbo ikilo Olorun ki a si se atunse ti o ye. Gbogbo orile-ede ati ahon nilati jewo Jesu Kristi ni Oluwa, ki won le jogun iye ayeraye. Ore ofe, Alafia, aseyori wa fun enikeni ti o ba ronupiwada ese won. Olorun yio layo lori enikeni ti o ba ronupiwada ti o si jewo Jesu Kristi ni Oluwa ati Olugbala re.
ADURA
Mo fi gbogbo re fun Jesu, patapata laiku kan, un o maa fe E, un o gbekele E, un o wa lodo Re titi, mo fi gbogbo re, mo fi gbogbo re, fun O, Olugbala mi, ni mo fi won sile. Jesu Kristi, Olufe, mo fi gbogbo aye mi fun o looni. Mo jewo re ni Oluwa ati Olugbala mi. Mo jewo ese mi, mo si ronupiwada kuro ninu won. Lati oni lo, emi yio sin o Pelu gbogbo agbara mi, emi yio tele o titi de opin. Jowo fun mi ni ore-ofe lati le mi iduro mi pelu re titi ojo aye mi, ki emi le jogun iye ayeraye lodo re ni orun. Ni oruko Jesu ni mo te pepe ebe mi Amin.
