NAANI ISE IGBALA TI JESU KRISTI SE FUN O
Onigbagbo ni a pe nija lati mo agbara tin be lehin igbala okan won, eyi ti won ri gba nipase Jesu Kristi. Ki a mase mu igbala wa pelu owo yepere, sugbon ki a mo riri re. Bibeli wipe ‘Awa o se laa, bi awa ko ba naani iru igbala nla bi eyi, ti atete bere si so lati odo Oluwa, ti a si fi mule fun wa lati odo awon eni ti o gbo. Olorun si n fi ise amin ati ise iyanu, ati oniruru ise agbara, ati ebu Emi Mimo ba won jeri gege bi ife re. (Heberu 2:3-4)
EKO
Pipese igbala fun eda eniyan ko rorun fun Jesu Kristi, o fi orun sile (pelu gbogbo itura re) lati wa si aye, o jiya inunibini lati odo awon ota re. Ni opin ohun gbogbo, Kristi ku ni ori igi agbelebuu, ki o le ri igbala fun eda eniyan. Nitori naa, ki omo Olorun ma se fi owo yeperu mu ore ofe igbala won. O ye ki a fi irele wa si ese Jesu Kristi ki a gbaa gege bi Oluwa ati Olugbala wa. Ati ni imoore Jesu fun ise igbala, o ye ki a fi otito sin Olorun pelu gbogbo okan wa.
ADURA
‘Mo ti se ileri lati tele Jesu, mo ti se ileri lati tele Jesu, mo ti se ileri lati tele Jesu, lai yi pada, lai yi pada (fi oruko re si) mo fi aye mi fun Jesu Kristi. Mo gbagbo pe oun ni omo Olorun, o ti san gbese ese mi, mo si ri idariji ese mi nipa re. Nitori naa mo jewo (Jesu Kristi) lati je Oluwa aye mi. Mo fi gbogbo aye mi fun, emi yio sin in pelu gbogbo ipa ati agbara mi. Emi yio sin in, maa si tele Jesu titi aye mi. Jowo Oluwa, fun mi ni ore-ofe lati sin o titi de opin. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
