WA NI IGBARADI
Olorun soro lati enu Wolii Jeremiah wipe oun yio pa run, agberaga orile ede ti o gbe ara re ga ju ife re. Olorun wipe ‘A o si pa Moabu run lati ma je orile-ede, nitori pe o ti gberaga si Oluwa (Jeremiah 48:42)
EKO
Gbogbo eniyan ni Olorun da, gbogbo eniyan ni yio jihin fun un. Ati Kristeni ati alaigbagbo ni a o jabo fun un. Eledaa kii se ojusaju, yio si se idajo ododo re lori gbogbo eniyan. Yio bukun enikeni ti o ba tee lorun yi o si fiya je elese ti ko ba ronupiwada. Gbogbo eniyan ni a ro ki won sin Olorun ninu otito, ki won si mu idapo won pelu re duro sin sin. O se pataki ki a mo pe enikeni ko le te Olorun lorun lai jewo Jesu Kristi ni Oluwa. Jesu Kristi je omo Olorun nitooto enikeni ko le ri Olorun bikose nipase re. (Johanu 14:6)
ADURA
Olorun Olufe, mo re ara mi sile niwaju re ki emi le ri igbala. Mo ronupiwada ese mi, mo si jewo Omo re Jesu Kristi ni Oluwa ati Olugbala mi. Mo yonda gbogbo aniyan mi fun o lati oni lo. Emi yio gboran si ase re, emi o si sin o ni gbogbo akoko aye mi ni otito. Jowo ka mi ye sinu ijoba re ayeraye. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
