JIJE OLUWA JESU KRISTI
Bibeli fi jije Oluwa Jesu Kristihan, kii se eda eniyan lasan, bi awon kan se gbagbo. O je Olorun ninu eniyan, nigba ti o wa sile aye, o si je bakannaa ni oni. A si koo wipe, Sugbon ni ti omo ni o wipe, ite re, Olorun, lae ati laelae ni, opa alade ododo ni opa, alade ijoba re, iwo fe ododo, iwo si korira ese, nitori naa ni Olorun, ani Olorun re se fi ororo ayo yan o ju awon egbe re lo. Ati iwo, Oluwa, ni atetekose ni o ti fi ipile aye sole awon orun si ni ise owo re. Won o segbe, sugbon, iwo o wa sibe gbogbo won ni yoo si gbo bi ewu. Ati bi aso ni iwo o si ka won, a o si paaro won, sugbon bakanaa ni iwo, odun re ki yio si pin. (Heberu 1:8-12)
EKO
Jesu Kristi ni ipinlese igbagbo, oun si ni alasepe igbala. Oun si ni asepe ife Olorun. O mu ki ofin Olorun rorun, o mu u to wa wa, Olugbala te kapeti aafin lati rin lori re, nitori naa enikeni ti o ba jewo re ni omo Olorun, ti o sigbaa ni Oluwa ati Olugbala re yio di eni igbala. Gbogbo eniyan kakiri ipo, ki won wa ni irele, ki won gba Jesu Kristi ni Oluwa ati Olugbala won. Enikeni ti o ba to Jesu Kristi wa ko ni kabamo, yio ni iye ainipekun ni orun.
ADURA
Jesu Olufe, mo mo wipe iwo ni Kristi omo Olorun ti o ku fun elese. O fi emi re rubo fun otosi elese bi emi, ki emi le jogun ebun iye ainipekun. Niwon bi o se daa si mi, mo wa fi gbogbo aye mi fun o. Mo jewo re ni Oluwa ati Olugbala mi, emi yio sin o fun gbogbo iyoku aye mi, lati akoko yi lo emi yio sin o fun gbogbo iyokuaye mi, lati akoko yi lo emi yio ma pin eri didara re simi pelu awon ore ati aladugbo mi. Emi yio kede ihinrere re ki awon eniyan le ni igbala. Jowo ran mi lowo lati le duro ti ijeri mi, ki emi si duro ti ileri re. Amin.
