OLORUN NI AGBARA TOO TO LATI GBEJA RE
Olorun pe awon Olugbe Judah lati dide fun ododo ati otito; ki won jawo ninu ireje awon ti ko ni agbara ati awon ti o ku kaato Judah yio gba ibukun, ti o ba le ran awon ara ti o ku lowo won yio jiya to buru ti won ba se ilodi si eyi. Jeremiah so asotele Bayi ni Oluwa wi, mu idajo ati ododo se ki o si gba eni ti a lo lowo gba kuro lowo aninilara, ki o ma se fi agbara ati ika lo alejo, alaini baba ati opo, beeni ki o ma se tae je alaise sile nihin-in yi. Nitori bi eyin ba se nnkan yi nitooto nigba naa ni awon oba yoo wole enu-bode ilu-yii, ti won o jokoo lori ite Dafidi, ti yoo gun keke ati esin, oun ati awon iranse re, ati eniyan re. Sugbon bi eyin ki yoo ba, gbo oro wonyi, Emi fie mi funra mi bura, ni Oluwa wi pe, ile yi yoo di ahoro (Jeremiah 22:3-5)
EKO
A ro awon omo Olorun lati se dara dara si gbogbo eniyan, laisi ojusaju. Lati fihan pe a je omo Olorun, ko ye ki a tee se ara wa mole. Ki a mase gba eto elomiran, ki a yago fun iwa imotara, eni nikan. Iwa wa (bi omo Olorun ni otito) ni lati se ipese fun awon ti ko ni to. Ki a ronu nipa aini awon eniyan wa, ki a pese fun awon omo ti ko ni obi, opo ati awon ti won ba wa nipo alaini. Inu Jehofa yio dun si wa bi a ban se awon nkan wonyi. Bi a ba tee lorun, o ye ki a maa reti ki o bukun wa, yio fa wa soke ju ibi agbara wa lo. Jehofa yio rii wipe a ko se alaini ohun kan.
ADURA
Olorun Olufe ran mi lowo lati je Oluranlowo fun awon ara to ku, Emi ko fe je (anikan je opon) oni imotara eni nikan, ti o nwa ipese fun ara re nikan. Je ki emi saanu fun awon eniyan, ki nsi pese fun aini won pelu gbogbo ipa mi. Jowo kun mi pelu Emi-Mimo, ki emi lee se ohun ti o to, ro mi ni ore-ofe lati ni okan rere si awon eniyan. Se mi ni olooto asoju nile aye, ki awon eniyan le layo, ki won si maa yin oruko mimo re. Lehin gbogbo nkan wonyi, bukun mi, ni gbagbo ona mi; ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin
