OLORUN NSE IYANU
Olorun ti se opolopo nkan ti o koja ogbon wa fun omo eniyan lati ri. Ogbon re jinle, a ko le se awari re. (Orin Dafidi) oni samu gbiyanju lati salaye didara Olorun o wipe o mu awon onirora okan lara da, o di ogbe won o ka iye awon irawo, o si so gbogbo won ni oruko Oluwa wa tabi ati alagbara nla, oye re ko ni opin (Orin Dafidi 147:3-5)
EKO
Olorun ni o tobi ju, oun ni o gaju gbogbo ohun ti o wa. O ni ase lati se ohun ti o ba wuu. Ona re gun, o si je olotito ni gbogbo igba. Olorun nse ohun ti o dara, o korira ise buburu. O nse daradara ni orisirisi ona. O nsaanu, gbe eniyan ga, o si nbukun awon ti o gbeke lee. Olorun ye fun iyin wa, gbogbo eniyan nilati maa yin in. Oye ki a maa yin in fun iyin wa, gbogbo eniyan nilati maa yin in. O ye ki a maa yin in fun ife re ti o jinle si wa. Gbogbo alaye okan lo ye lati korin, ki won si ke Halleluyah si Olorun iyanu ti o sin se iyanu ni gbogbo igba. Je ki alaye okan ke Halleluya.
ADURA
Mo feran re Olorun fun ise amin ati iyanu ti o ti se fun eda eniyan. Mo dupe gidigidi fun awon ohun didara ti o se ninu aye mi. O se fun ewa ojojumo ti mo nri. O seun fun oorun, osupa, ofurufu, irawo. O seun fun afefe, o seun fun awon ohun afojuri ti o da, o sefun fun ana, oni ati ojo ola pelu. O seun fun awon ohun rere ti mo ni, emi o si maa yin o titi laelae. Ni oruko Jesu Kristi ni mo mu gbogbo iyin wa. Amin
