MA SE SO IRETI NU NIGBA IDANWO
Ni opo igba, a maa nsi awon iranse Olorun gbo, ki a bu won, ki a dawon lejo. Sugbon Eledaa yio san esan fun iranse re ti o ba fi otito duro titi dopin. Paulu salaye iriri re nipa eebu ti araye fi bu nitori ijolooto re si Olorun. Paulu wipe nitori mo ro pe Olorun ti yan awa Aposteli keyin bi awon eni ti a da lebi iku, nitori ti a fi wa se iran wo fun aye, ati fun angeli, ati fun eniyan. Awa je asiwere nitori Kristi, sugbon eyin je ologbon ninu Kristi; awa je alailera, sugbon eyin je alagbara; eyin je olola, sugbon awa je eni egan. Ani titi fi di wakati yi li ebi npa wa, ti orungbe si n gbe wa, ti a si wa ni ihoho, ti a si nlu wa, ti a ko si ni ibugbe kan. Ti a nse laalaa, a nfi owo ra wa sise; nwon gan wa, awa msure; nwon se inunibini si wa, awa nforiti i. Won nkegan wa, awa mbebe, a se wa bi ohun egbin aye, bi eeri ohun gbogbo titi di isisiyi (1 Korinti 4:9-13)
EKO
Awon iranse Olorun maa ba atako pade, won maa nse inunibini si won, won si maa ndojuko atako ti o buru. Jehofa yio o san esan nla fun iranse re ti o ba fori tii ni akoko idanwo yio ran won lowo ni aye yi, yio si b’ola fun won ni orun. Nitori naa, enikeni ti o ba nsin Olorun ni ipokipo, ki o mo wipe ise re ko ni jasi asan. Awon eniyan ti won ba ri inunibini ti won si duro sin sin pelu Olorun, won yio gba anfani re. Eledaa yio se oruko re logo ninu aye won, gbogbo eniyan (ati Keferi) ni yio ri amulo agbara, ore-ofe ati igbala.
ADURA
Olorun Olufe, jowo se mi ni olotito iranse ti yio duro ti o ni gbogbo igba. Mo si gbadura fun gbogbo iranse re ni gbogbo agbaye. Jowo fun won ni igboya ati agbara lati sin o bo ti ye. Ran wa lowo lati mu ni koko lati sise fun o. Je ki gbogbo igbiyanju wa ki o mu eso wa sinu ijoba re. Je ki gbogbo akitiyan wa ki o yori si igbala okan, ki oju le ti Satani, ki oruko re di yin yin. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere Amin.
