YIN OLUWA
Ohun elo orin dara lati maa fi yin Olorun, a ni lati loo lati tee lorun. Oni Samu (Orin Dafidi) ro wa lati maa yin Eledaa wa pelu awon ohun elo ti a se pelu owo wa, o wipe ‘E fi iyin fun Oluwa, E fi iyin fun Olorun ninu ibi mimo re, yin in ninu ofurufu oju orun agbara re. Yin in nitori ise agbara re, yin in gege bii titobi nla re. Fi ohun ipe yin in, fi ohun-elo orin ati duru yin. Fi ihu ati ijo yin in fi ohun ona orin olakun ati fere yin in. E yin in lara aro, olohun oke, e yin ni lara aro olohun gooro. Je ki ohun gbogbo ti o ni emi ki o yin Oluwa. E fi iyin fun Oluwa (Orin Dafidi 150: 1-6)
EKO
Olorun ko ni je ounje ti a le foju ri, sugbon a maa je iyin, Aa ma yo ninu iyin ti awon Omo re nfi fun-un. O nb’ola fun iyin ati isin ju ohun kohun lo. Jehofa mo iyi ijosin ti o ni awon elo ti a fi ogbon ori see. O se Pataki, ki gbogbo eniyan ronu ona ti a ngba ni yinyin Olorun. Iyin ti o ba jinle pelu otito yio mu ibukun Oluwa wa. Ti awa ba fi imore han, baba wa tin be lorun yio rojo ibukun, a o si ri idi yin yin oruko re.
ADURA
Olorun jowo ko mi bi mo se le maa yin o lotito. Emi yio bere si nyin O lati akoko yi lo. Emi yio yin o fun opolopo oore re ninu aye mi. O ti mu mi jade kuro ninu erofo wa si ori apata. O ti fun mi ni orin titun, o si fun mi ni opolopo ibukun. Emi yio kegbe iyin oruko re, emi yio sin O lati erekusi kan si ikeji, un o si maa jeri si didara re si mi nigba gbogbo. Jowo je ki nmaa fokan imore han nigba gbogbo ki emi je itoka iyin si oruko Jesu Kristi ni mo beere, Amin.
