OLORUN KORIRA IWA IBALOPO AIMO
Awon omo Olorun ni lati sa gbogbo ipa won lati yera fun ese ibalopo, niwon bi o ti je ohun irira si Olorun. Bibeli kilo fun awa Kristeni lati mo wipe, o je ese nla, ese ibalopo. A ti koo wipe, Emi ti kowe si yin ninu iwe mi pe, ki e ma se ba awon agbere kegbe po. Sugbon kii se pelu awon agbere aye yii patapata, tabi pelu awon olojukokoro, tabi awon alonilowogba, tabi awon aborisa nitori nigba naa, e ko le sai ma ti aye kuro. Sugbon nisisinyi mo kowe si yin pe, bi enikeni ti anpe ni arakunrin ba je agbere tabi olojukokoro, tabi aborisa, lati elegan, tabi omutipara, tabi alonilowogba, ki e ma se baa kegbe, iru eni bee, ki e ma tile baa jeun. (1 Korinti 5:9-11)
EKO
O je ohun iyi ati iwuri ki Kristeni duro sisin pelu Olorun ninu iwa mimo, o si je ohun itiju ati irira fun Kristeni lati dese ibalopo. Olorun korira ese ibalopo, ko si fe ki awon omo re kopa ninu re. Enikeni ti o ba ronupiwada kuro ninu ese ibalopo yio ri ibukun Olorgun gba. Yio ka ibukun re kuro lori awon ti o ntesiwaju ninu ese ibalopo. Ki gbogbo eniyan ye ara won wo ki won se atunse ti o baye, ki won maa rin dede pelu Olorun ninu igbe aye iwa mimo.
ADURA
Olorun Olufe, gba mi lowo ese ibalopo, da okan funfun sinu mi, da aya titun sinu mi. Mo kaanu fun awon ese ti mo ti da, mo kaanu fun ese ibalopo ti mo da. Jowo je ki emi ni ibere otun. Je ki emi maa sin o ninu ewa iwa mimo re. Ki emi maa rin deede ni gbogbo igba. Je ki Emi Mimo ki o di mi mu titi di ipadabo re, ni igba keji. Jowo ko oruko mi sinu iwe iye, si ka mi ye lati je alaba pin ninu ase ijoba orun. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere Amin.
