OLORUN DA ENIYAH YAJO
Adamu ati Efa ni ibere iran eda eniyan, won bi Kaini ati Abeli ati Seti. Abeli ati Seti si bimo, awon omo won si bimo. Omo bibi si ntesiwaju sii. Eniyan ngbile lorile aye, lati maa je igbadun ipese Olorun. Die ninu awon omo Adamu ti a daruko ni wonyi ‘Adamu, Seti, Emosi, Kenani, Mahaleeli, Jeredi, Kenoki, Metusela, Lameki, Noa, Semu, Hamu, ati Jefeti (1 Kronika 1:1-4)
EKO
Olorun da eniyan ki a le gbile lori ile aye ti o da. Laarin ogunlogo ohun ti o da, o da eniyan yato. O fun wa ni ‘OKAN ENIYAN’ Olorun si omo eniyan ko see salaye. Eyi ti a le se ni ki a mo riri isore Olorun - Eledaa, ki a si fi okan otito sin in.
ADURA
Mo dupe lowo Olorun alagbara ti o da mi ni aworan ara re. Mo fokan imore han ti o fun mi ni Emi ati okan. Mo dupe gidigidi pe Olorun da mi ni eniyan, o si fun mi ni ase lati joba lori ohun gbogbo ti o da. Ohun ti mo nbeere ni wipe ki Olorun fun mi okun lati lee maa tee lorun pelu igbe aye mi. Mo bebe fun ore-ofe ati aanu, ki emi le se bo ti nfe, ki a le toka si mi bi omo ti o mo oore. Ki ore-ofe Olorun alagbara to fun mi loni ati titi ayeraye. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin
