OLORUN PESE ORUN APADI FUN AWON ENIYAN BUBURU
Olorun korira iwa buburu, ko si ni da awon eniyan buburu si lai gba ijiya won. Bibeli wipe Olorun yi o pon awon eniyan buburu loju ninu ina orun apadi. A koo wipe Oluwa nda olododo wo, sugbon eniyan buburu ati eni ti o fe iwa ipa, ni okan re korira. Lori eniyan buburu ni yoo rojo eyin ina ati imi-ojo ati iji gbigbona, eyi ni ipin aago won. Nitori olododo ni Oluwa, o fe ododo, awon eniti o duro sinsin yoo ri oju re.
(Orin Dafidi 11:5-7)
EKO
Olorun fe fiyaje araye fun iwa buburu won ni a ko si nu bibeli. Majemu laelae ati Majemu titun so wipe Olorun yi o fi opin si aye buburu yi, yi o si daa si orun ina apadi, ati awon alaironupiwada elese. Lehin pipa aye yi run, Olorun yi o ko awon eniyan mimo re jo sinu aye titun ati orun titun ti o ti pese fun won. (Ifihan 21:1-5)
Jesu Kristi pese ona kan soso fun abayo kuro ninu orun ina apadi. Enikeni ti o ba gba Jesu Kristi ni Oluwa ati Olugbala re, yi o rekoja idajo orun ina apadi Olorun ni ojo ikehin. Die ninu ese bibeli ti o toka si Pataki eredi wa lati ronupiwada ati jijewo Jesu bi Oluwa ni a ko nisale yi.
1. Orin Dafidi 11:5-7 (Olorun dan olododo wo, sugbon eni buburu ati eni ti o feran iwa ipa ni okan re korira. Lori eniyan buburu ni yi o rojo ina, Eyin na ati imi ojo ati iji gbigbona, eyi ni ipin aago won. Olorun je olotito, o feran otito.
2. Orin Dafidi 49:13-14 ipa ona wonyii ni igbeke won, oro won si to ni oju awon omo won. Bi aguntan ni a nte won si isa-oku, iku yoo jeun lara won, eni diduro-sinsin ni yoo joba won ni owuro, ewa won yoo si re kuro, isa oku si ni ibugbe won.
3. Matiu 25:41 Nigba naa ni yoo si wi fun awon ti owo osi pe, elo kuro lodo mi, eyin eni egun, sinu ina ainipekun, ti a ti pese sile fun Esu ati fun awon angeli re.
4. Matiu 10:28 Ema beru awon eniti ipa ara, sugbon ti won ko le pa okan. Sugbon e kuku beru eni ti o le pa ara ati okan run ni orun apadi.
5. Johanu 14:6 Jesu wi fun un pe, Emi ni ona ati otito ati iye, ko si enikeni ti o le wa sodo Baba, bi ko se nipase mi.
ADURA
Oluwa Olufe, o to gee emi ko fe lo si orun ina apadi, sugbon mo fe lo si orun. Mo setan lati dake fifi ina sere. Lati oni lo mo yonda fun o (Jesu) Emi, okan ati ara mi. Mo fi gbogbo aye mi, mo si jewo re ni Oluwa. Mo jewo pe Jesu Kristi ni omo Olorun, o ku o si ji dide, oun si ni Oluwa ati Olugbala mi. Mo jewo ese mi, mo si ronupiwada won. Lati akoko yi, mo di omo Olorun. Mo ko ese ati gbogbo ise esu. Mo ba majemu mi pelu esu je, mo si yan majemu titun pelu Jesu Kristi. Mo kede ni gbangba (so oruko re) pe mo je atunbi Kristeni, orun si ni ile mi. Amin!
