OLORUN FE KI A RONUPIWADA
Awon Farisi gba pe Jesu Kristi je Olukoni won si gba pe oun ni Mesaya ti won nreti. Nitori naa awon Farisi de awon sile fun isubu Jesu Kristi. Won dan an wo pelu oniruru ibere rikiosi, pelu ireti ki o le subu ninu oro re ikan nipa alaye awon Farisi niyi. Awon akowe ati awon Farisi si mu obinrin kan wa sodo re, ti a mu ninu pansaga, ninu sisee paapaa nje ninu ofin Mose pase fun wa lati so iru awon bee ni okuta pa, sugbon iwo ha ti wi? Eyi ni won wi, wondan on wo, ki won baa le ri ohun lati fii sun, sugbon Jesu bere sile, o si nfi ika re kowe ni ile. Sugbon nigba ti won nbii leere sibesibe, o gbe ara re soke, o si wi fun won pe, eni ti o ba se alaise ninu yin, je ki o so okuta luu. O si tun bere sile, o nkowe ni ile. Nigba ti won gbo eyi, won si jade lo lokookan, bere lati odo awon agba titi de awon ti o kehin, a si fi Jesu nikan sile ati obinrin naa laarin, nibi ti o ti wa. Jesu si gbe ara re soke, o si wi fun un pe, Obinrin yii, awon da? Ko si enikan ti o da o lebi?
(Johanu 8:3-10)
EKO
Olorun ko ni inu didun lati da enikeni lejo ki a si soo sinu ina orun apadi. Eleeda ni inu didun si ironupiwada elese. O fe ki gbogbo eniyan ronupiwada ese won, ki o si gba Omo re Jesu Kristi gege bi Oluwa ati Olugbala re. Enikeni to o ba gbagbo ninu Jesu, ko ni ni ipin ninu ijiya orun apadi. Sugbon elese ti ko ba ronupiwada ni a o ko sile ni orun, a o si so si ina orun apadi. (Niwon bi Jesu se je alaanu, ko ni ko sile enikeni ti o ba gbagbo ninu re) ona si igbala rorun o si je ofe. Igbala je ki eniyan jewo igbagbo re ninu Jesu Kristi.
ADURA
Jesu Kristi Olufe, mo jewo pe iwo ni Omo Olorun ti o ku fun ese gbogbo araye. O ti ku o si jidide lati fun mi ni iye ainipekun, nitorina mo jewo re ni Oluwa ati Olugbala mi. Mo jowo gbogbo aye mi fun o, emi yi o sin o fun gbogbo iyoku aye mi. Jowo ko oruko mi sinu iwe iye, si ka mi ye lati le yayo pelu re ni orun rere. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
