JESU KRISTI KII SE ENIYAN
Jesu Kristi ko awon Farisi ni awon otito ti o koro, ti o ru ibinu won soke. O wipe Abrahamu baba yin yo lati ri ojo mi, o si rii o si yo. Nitori naa awon Juu wi fun un pe, odun re ko tii to aadota, iwo si ti ri Abrahamu? Jesu si wi fun won pe, ‘looto, looto ni mo wi fun yin, ki Abrahamu to wa, emi ti wa‘. Nitori naa won gbe okuta lati so luu, sugbon Jesu fi ara re pamo, o si jade kuro ni tempili
(Johanu 8:56-59)
EKO
A bi Jesu Kristi sinu aye bi Omo eniyan sugbon o ju eniyan lo. O je Olorun ninu eniyan. Lotito nigba ti Jesu wa laye, o rin bi eniyan, o soro bi eniyan, sugbon kii se eniyan lasan, oje atunda Olorun. Bibeli jeri pe Jesu je Olorun ni aworan ara eniyan, nigba ti o wipe ‘Ni atetekose ni oro wa, oro si wa pelu Olorun, Olorun si ni oro naa; oun naa ni o wa ni atetekose pelu Olorun. Nipase re ni a ti da ohun gbogbo, leyin re a ko si da ohun kan ninu ohun ti a da. Ninu re ni iye wa, iye naa si ni imole araye imole naa sin mole ninu okunkun, okunkun naa ko si bori re. (Johanu 1:1-5)
ADURA
Jesu ni Olorun ni aworan ara eniyan, oun si ni Oluwa, mo ni idaniloju pe Jesu ni Olugbala gbogbo aye. Nitori naa mo fi gbogbo aye mi fun un. Mo tun nso lekan sipe, gbogbo aye mini mo jowo fun Jesu Kristi. Mo pase ki Satani jade kuro ninu aye mi, niwon bi mo ti di Omo Olorun. Mo se ijewo mi nipa agbara ati ase ti mbe ni oruko Jesu Krist. Amin.
