A NI LATI GBEKELE LE OLORUN
Dafidi salaye bi o se ni ifakonbale lehin igba ti o fi igbekele re sinu Olorun, okunrin na wipe. Emi ti gbe Oluwa ka iwaju mi nigba gbogbo, nitori o wa ni owo otun mi, a ki yoo si mi ni po. Nitori naa ni inu mi se dun, ti okan mi si inyo, ara mi pelu yoo sinmi ni ireti.
(Orin Dafidi 16:8-9).
EKO
Gbogbo eniyan ni lati gbeke le Olorun, ki a le ni ifokanbale ati irorun, ohun gbogbo ni yi o wa leto leto fun eni to ba gbekele Olorun. Eleda yio se akoso aye eni naa, oun o ni eri didara lati pin pelu awon eniyan. Nitori naa, gbogbo eniyan nilati gba Olorun gbo.
ADURA
Olorun Olufe, bi emi ko ba gba o gbo, tani emi o wa gbagbo? Ko si! erongba mi ni lati gbeke le o ninu ipokipo ti mo ba wa. Mo gbadura ki o fun mi ni ore-ofe lati gbeke le o. Ro mi ni agbara Emi Mimo ki emi le pe o, ki emi si gbeke le o, si gbo eto/ilepa aye mi, ki emi le se aseyori. Jowo bukun mi, ki emi si je anfani didara re fun iyoku gbogbo aye mi. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
