SATANI AMA TAAKO AWON ONIGBAGBO
Jesu Kristi se ise iyanu ti gbogbo eniyan (awon alatako re) ko le foju fo Mesaya ni gbangba se ipese oju meji fun okunrin afoju kan ti o beere fun iranlowo. Bi o ti je pe ise iyanu Jesu tobi ju ohun ti a lee foju fo, awon Farisi si mokan le lati wa awawi lati se atako re, awon alatako Jesu so wipe koye ki o se ise iyanu ni ojo isimi. Bibeli wipe nigba ti o ti wi bee tan, o tuto sile, o si fi ito naa se omo, o si fi amo naa pa oju afoju naa. Osi wi fun un pe, lo we ninu adagun Siloamu (itumo eyi tii je Ran lo) nitori naa o gba ona re lo o we o si de, o n riran. Won si mu eni ti oju re ti fo ri wa sodo awon Farisi. Nje ojo isimi lojo naa nigba ti Jesu se amo naa, ti o si laa loju. Nitori naa awon Farisi pelu tun bii leere, bi o ti se riran, o si wi fun won pe, o fi amo le oju mi, mo si wi, mo si reran. Nitorinaa awon kan ninu awon Farisi pelu tun bii leere, bi o ti se riran, o si wi fun won pe, okunrin yii ko ti odo Olorun wa, nitori ko pa ojo isimu mo. Awon elomiran wipe, okunrin tii se elese yoo ha ti se le se iru ise ami wonyi, iyapa si wa laarin won (Johanu 9:6-7, Johanu 9:13-16).
EKO
Talo fe te awon alagabagebe lorun? Kii se emi. Alatako ko le ri idi lati yo mo ohun ti o dara, sugbon yi o ma wa ona lati wa awawi si awon eniyan ti o sise daradara. Otiti ti o koro ni pe awon atele Satani yi o maa tako Kristeni nigba gbogbo. Eredi won ni lati mu wa rewesi ninu igbiyanju wa, sugbon omo Olorun ko ni lati kobi ara si idojuko Satani. Eyi ti a o fi maa da awon alatako lohun, ojuse wa ni ki a waasu ihunrere, ki a si se ife Olorun ni oju idojuko ati alatako. Olorun ni esan nla fun awon omo re ti o ba durosinsin ninu igbagbo. Jehofa yi o wo awon olotito atele re ni ogo ati ola, yi o si mu ki oju won maa da.
ADURA
Oluwa Olufe to dara, mo setan lati te o lorun, ohunkohun iba maa naa mi, lai san ohunkohun fun Satani ati awon omo lehin re. Jowo fun mi ni ifami ororo yan ore ofe lati le duro sinsin, ki emi si te o lorun ninu ise iranse mi. Mase je ki ngba awon eniyan buburu laye lati wa simi lona ninu ise didara mi. Ran mi lowo ki emi le se ise ti o fun mi lati se ki emi si se fun itelorun re. Jowo fun mi ni aseyori ni aye ati ni orun. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
