TITOBI AGBARA OLORUN
Dafidi oba mo Olorun daradara, o si fun ni aye lati je igbadun anfani re nigbesi aye re. Dafidi salaye Olorun, o si wipe, ofin Oluwa pe o nyi okan pada, eri Oluwa dani loju, o n so ope di ologbon. Ilana Oluwa to, o nmu okan yo, ase Oluwa ni mimo, on se imole oju. (Orin Dafidi 19:7-8).
EKO
Agbara Olorun tobi, yi o si maa joba titi ayeraye. Jehofa lo ni gbogbo agbaye, o ni agbara lati dari ohun gbogbo lati te ara re lorun. Nitorina enikeni ti o ba yan lati je ore Olorun yi o je opolopo anfani re. Awon ti o ba warun ki si Olorun yi o gba ijiya won ni orun ina apadi.
ADURA
Olorun Olufe, mo mo pe iwo yi o bukun awon ore re ni orun rere, oofiya je awon ota re ni orun ina apadi, mo di ore e. Jowo dari ero okan mi ati ise mi, ki emi ki o ye fun anfani re. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
