MASE FAYE GBA IYEMEJI
Okunrin afoju ti Jesu wo san, mo riri iwosan re, o yin Jesu logo awon Farisi nse idena fun un ki o ma baa se bee. Nigba ti awon Farisi so pe elese ni Jesu, okunrin naa tenu moo wipe bi elese ni, emi ko mo, ohun kan ni mo mo, pe mo ti foju ri, mo riran nisinyi. Awon Farisi te siwaju lati mu ki okunrin se Oluwosan re. Nitorinaa won wi fun un pe, kini o se si o? O ti se la o loju? O dawon lohun wipe, Emi ti so fun yin na, eyin ko si gbo, nitori kin ni eyin se nfe tun gbo? Eyin pelu nfe se omo ehin re bi? Won si fii se eleya won si wipe, iwo ni omo-ehin re, sugbon omo-ehin Mose ni awa. Awa mo pe Olorun ba Mose soro, sugbon bi o se ti eleyi, awa ko mo ibi ti o gbe ti wa. (Johanu 9;25-29).
EKO
Olukuluku ni lati gba ise iyanu re lodo Olorun pelu igbagbo. Ki a mase je ki iyemiji, ati idojuko ota di idiwo fun wa nipa gbigba ise iyanu wa. Bibeli wipe olododo ni yoo ye nipa igbagbo, (Heberu 10:380 Nitorina, a ni lati mo wipe ko si eni ti o le je anfani Olorun bikose nipa igbagbo.
ADURA
Olorun Olufe, mo loye pe igbagbo je ara ohun ti o se Pataki fun Kristeni, enikeni ko si le gbadun re laisi igbagbo. Mo beere ki o jowo bukun mi pelu ore-ofe, ki emi ni igbagbo ninu re, je kinle lo igbagbo ninu ohunkohun ti mo ban se. Si fun mi ni igboya ni gbogbo igba lati maa yayo anfani re ninu aye mi. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
