image

ADURA SE KOKO

Dafidi gbadura taara, ti o ni sise pelu gbogbo eni ti o ba fe je ninu anfani lodo Olorun. Dafidi okunrin wipe ki Oluwa ki o gbohun re ni ojo iponju, oruko Olorun Jakobu ki o dabobo o. Ki o ran iranlowo si o lati ibi mimo wa, ki o si ti o leyin lati Sioni wa. Ki o ranti ebo ore re gbogbo, ki o si gba ebo sisun re. Ki o fi fun o gege bii ti inu re ki o si mu gbogbo imo re se.

 

(Orin Dafidi 20:1-4)

 

EKO

 

Adura se Pataki lati fa agbara Olorun si ohun gbogbo ti o ban se, a ro onigbagbo lati fi edun okan re han si Olorun nipa adura, ki won salaye ara won fun Olorun. Ki won bee ki o gbakoso. Onigbagbo nilati ni igbagbo lehin ti a ba ti gbadura si Olorun. Adura igbagbo yi o je ki Emi Olorun dari ohun gbogbo, yi o si bori ogun wa. Igbagbo wa yi o ran onigbagbo lowo lati yin Olorun logo nigba ti a ba ti ri idahun si ibere wa.

 

ADURA

 

Ni oruko Jesu Oluwa, mo pase ki gbogbo ipenija aye mi ki won teriba. Mo ba Satani wi, ki o yowo idoti re kuro ninu aye mi. Mo pase ki aisan, osi, ijakule, ese ati gbogbo ise Satani ki o kuro ninu aye mi. Mo gba isegun mi looni, ni ola ati titi aye ni oruko Jesu Kristi. Amin .

Video Version


Subscribe To Channel

Audio Version


Download Audio
Posted By: James Taiwo