OLORUN LEBORI GBOGBO ISORO WA
Jesu Kristi se iwosan fun Okunrin kan leti bode aguntan, bi okunrin naa ko tile le wo oju oluwosan. Arakunrin je ki isoro re wo o ni okan to bee ti ko le dahun ibeere ti o kere, nigba ti Jesu oluwosan wa sodo re, bibeli wipe Okunrin kan si wa nibe, eni ti o wa ni ailera re ni odun mejidinlogoji. Bi Jesu ti rii ni idubule, ti o si mo pe, o pe ti o ti wa bee, o wi fun un pe iwo fe ki a mu o larada bi? Abirun naa da lohun wipe, ogbeni, emi ko ni eniti iba gbe mi sinu adagun nigba ti a ba ru omi na bi emi ba ti nbo wa, elomiran a sokale sinu re siwaju mi. Jesu wi fun un pe dide gbe akete re, ki o si maa rin. Logan, a si mu Okunrin na larada, o si gbe akete re, o si nrin, ojo naa si je ojo isinmi. (Johanu 5:6-9).
EKO
Enikeni ko ye ki o doju ko isoro re ju Olorun lo. A ro gbogbo wa lati koju si Olorun, iru igbenija ti o wu ki o yi wa ka. Olorun ni idahun si gbogbo isoro ti o doju ko wa. O ni agbara lati yanju isoro wa, bi o ti wu bo ti tobi to. Ko si enikan ti o le yanju isoro ara re nipa yiyee wo, sugbon isoro le di yiyanju bi Olorun ba da sii. Koko oro nipe, isoro yi o tobi bi a ba doju ko o, sugbon yi o kere bi a ba doju ko Olorun. O je ohun ti o dara, bi a ba le fokan tan olorun ninu iriri aye ti a le ba ara wa.
ADURA
Olorun olufe, jowo, bukun mi ni ore ofe lati le doju ko o ninu ohun gbogbo. Mase je ki isoro wo mi ni okan, sugbon je ki n gbe o sokan mi, fun mi ni ore ofe lati gbagbo pe o o yanju isoro mi, iwo yi o si segun fun mi ni gbogbo igba. Dipo irora ati ijiya, fun mi ni ayo. Fun mi ni oju didan pelu ororo inudidun, ki emi maa yayo awon anfani re fun iyoku igbe aye mi. Ni oruko Jesu ni mo beere. Amin.
