OJO IDAJO OLUWA
Jesu Kristi kede fun gbogbo eniyan wipe, igbala oun nikan ni amuye fun enikeni ti o ba fe wonu ijoba olorun. Eni ti o ba ko eto igbala Jesu ko le nipin ninu ijoba olorun. Looto, looto ni mo wi fun yin, enikeni ti o ba gbo oro mi, ti o ba si gba eni ti o ran mi gbo, o ni iye ti ko nipekun, oun ki yoo si wa si idajo, sugbon o ti re iku koja bo si iye. Looto looto ni mo wi fun yin, wakati naa nbo, o si de tan, nisisiyi, nigbati awon oku yoo gbo ohun omo olorun, awon ti o ba gbo yoo si ye. Nitori pe, gege bi baba ti ni iye ninu ara re, gegebe ni o si fi fun omo lati ni iye ninu ara re. O si fun un ni ase lati maa se idajo pelu, nitori ti oun ise omo eniyan.
EKO
Ojo idajo Oluwa yi o wa fun gbogbo eniyan. Ati oku ati alaye ni yi o doju ko ite idajo, eleda yi o ran awon elese ti ko ronupiwada lo si adagun ina orun apadi, sugbon awon elese to ti ronupiwada lo si orun rere. Awon ti a pe ni elese to ronupiwada ni awon ti won ti ronupiwada ese won, ti won si ti gba Jesu Kristi gege bi oluwa ati olugbala won. Alaironupiwada elese (oku tabi alaye) ni awon ti o ko lati jewo Jesu Kristi ni omo olorun, ti won si ko lati gbaabi Olugbala won.
ADURA
Jesu Kristi, emi ko fe lo si orun ina, sugbon mo fe lo si orun rere. Nitori na mo jewo pe iwo ni omo olorun ti o ku fun ese gbogbo araye. Mo gba Jesu Kristi gege bi Oluwa ati Olugbala mi, mo ronupiwada ese mi, emi o si maa fi otito sin o lati akoko yi lo, ati ni gbogbo ojo aye mi lo. Ki olorun ran mi lowo. Amin.
