OGBON TO TAYO NIPA ORO OLORUN
Ogbon ti o yato ni o maa nfun awon ti o ba nkeko oro Olorun. Orin Dafidi wipe Emi ni oye ju gbogbo awon oluko mi lo nitoripe eri re ni isaro mi. Oye ye mi ju awon agba lo, nitori ti mo pa eko re mo (Orin Dafidi 119:99-100)
EKO
Enikeni ti o ba nkeko bibeli ni ojojumo ko ni kabamo titi aye. Oro Olorun yio si wa niye si ogbon ti yio mu ki a logbon sii, ki a si ni agbara. Nitori eyi, ki gbogbo omo Olorun maa keko inu bibeli ni ojoojumo, ki won le je anfani didara Olorun, ki won si maa tan ogo re.
ADURA
Olorun Olufe jowo je ki emi maa keko oro re ni ojojumo. Ro mi ni agbara, ki emi le duro ninu oro re, ki emi le se rere, ki nsi je ibukun re ni ile alaye. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
