AWON AMI IPADABO JESU KRISTI LEKEJI
Bibo Jesu Kristi nigba keji yio dabi igba ti eniyan nla ala ni osan. Yio sele lojiji, yio si ba opolopo ni abo (aimurasile). Bibeli wipe nitori pe eyin tikara yin mo daju daju pe ojo Oluwa nbo wa gege bi ole ni oru. Nigba ti won baa nwipe alaafia ailewu, nigba naa ni iparun ojiji yio de sori won gege bi irobi lori obinrin ti o loyun won ki yio si le sala (1 Tesalonika 5:2-3).
EKO
Jesu Kristi ko ni ranse si enikeni nipa igba ifarahan re ni oju ofurufu, lati gba awon eniyan mimo soke. A ti ri awon ami nipa igbasoke ati awon ohun ti yio saaju re. Jesu Kristi yio gba awon eniyan mimo soke orun, sugbon awon alaigbagbo yio wa laye, Satani yio fiya je won. Olorun yio ju Satani ati awon ti satani segun sinu ina – ina orun apadi. Nitorina gbogbo eniyan nilati kiyesi awon isele ni aye, ti o ntoka si dide opin aye. Gbogbo eniyan ni ki o gbiyanju lati di omo Olorun. A nilati jewo Jesu Kristi bi Oluwa ati Olugbala wa.
ADURA
Jesu Kristi Olufe, mo mo wipe, oo fara han nigba kigba lati gba awon eniyan mimo soke orun, mo si fe igbasoke. Nitori naa, mo ronupiwada kuro ninu ese mi, mo si jewo Jesu Kristi ni Oluwa ati Olugbala mi. Emi yio fi otito sin o lati oni lo, jowo ko oruko mi sinu iwe iye, emi si mura sile igbasoke lo si orun. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
