MA TUN SE ILERI ASAN ATI OFO NIWAJU OLORUN
Onidajo Jefta ba ara re laarin okuta ati ibi ti o le nipa sise ileri tabi jeje eje ti ko se yipada. O je eje pe bi Olorun ba fun un ni isegun larin awon ota re, oun yi o se irubo nla si Olorun. Jefta wipe ‘Yoo si se ohunkohun ti o ba ti ilekun ile mi wa pade mi, nigba tiemi ba ti odo awon Amoni pa dabo ni Alafia, ti Oluwa ni yoo je, emi o si fi ru ebo sisun. Olorun gbo adura Jefta, sugbon omo bibi re kan soso ni o wa pade re ni enu ona re, ti o jasi pe yi o fi se irubo si Olorun. (akiyesi, iru ebo yi ko tona ni akoko tiwa yi) bibeli wipe ‘Jefta si pada si ile re ni Mispa, si kiyesi, omobirin re si jade wa pade re ti timbrili ati ijo, oun nikan si ni omo re, leyin re koni omokunrin tabi omobirin. Nigba ti o rii, o fa aso re ya, o si wipe, omo mii, iwo re mi sile gidigidi, iwo si ni okan ninu awon ti nyo mi lenu, nitori emi ti ya enu mi si Oluwa, emi ko si le pada. Oun si wi fun pe, baba mi, iwo ti ya enu re si Oluwa, se si mi gege bi eyi ti o ti enu re jade, niwon bi Oluwa ti gbesan fun o lara awon ota re, ani lara awon omo Amoni. (Awon Onidajo 11:34-36)
Sibe Jefta mu ileri re se, bi o tile maa na ni ohun nla. O bowo fun Olorun, o si fi omobirin kan ti o ni rubo si Olorun.
EKO
O ye ki ama bowo fun Olorun nigba gbogbo. Anilati bu ola fun ki a si mu ileri wa se. a ko ni lati se ileri alailemuse niwaju Olorun, a ni lati kiyesi awon oro wa bi won se tobi to nitori Olorun ko mo awada. Yi o di ileri wa mu, yi o si duro de mimuse lai ka ohun ti yoo na wa. Yi o beere fun eto re titi a o fi muse. Anilati sora ki a mase se ileri ofo fun Olorun. Ni ona miran Olorun yi o bukun enikeni ti o ba mu ileri re se, yi o si se ohun ti yi o mu ki eni bee tun se ileri miran ni ojo iwaju.
ADURA
Olorun olufe jowo ran mi lowo ninu oro ati ninu ise. Je kinle mu awon ileri mi se. je ki imuse awon ileri mi si opolopo ilekun anfani si nu aye mi, kinsi je anfani didara re ni ile alaye. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
