IPE SI IRONUPIWADA
Jesu Kristi fi Olorun se akawe okunrin oloro kan ti o ni ilepa ti ko si gba ohunkohun laye gege bi idiwo. A so itan aye oloro naa o si wipe ‘Okunrin kan se ase-ale nla, o si pe eniyan pupo. O si ran omo-odo re ni wakati asa-ale lati so fun awon ti a pe wi pe E wa, nitori ohun gbogbo se tan. Gbogbo won si bere ni ohun kan lati se awawi, ekini wi fun un pe mo ra ile kan, emi ko si le se ki nma lo woo mo be o, se gafara fun mi. enikeji si wi pe, mo ra ajaga maalu marun-un, mo si nlo dan won wo mo be o se gafara fun mi. eketa si wi fun pe, mo gbeyawo nitorina ni emi ko fi le wa. Omo-odo na si pada lo, o so nnkan wonyi fun oluwa re, nigba naa ni bale ile binu, o wi fun omo-odo re pe, jade lo si igboro ati si Abuja ona, ki o si mu awon talaka ati awon alabuku arun ati awon amukun-un, ati awon afoju wa si ihinyi. Omo odo naa si wipe, Oluwa, a ti se bi o ti pase, aye sin be sibe. Oluwa naa si wi fun omo-odo naa pe, jade lo si opopo, ati si ona ogba, ki o si ro won lati wole wa ki ile mi lekun. Nitori mo wi fun yin, enikeni ninu awon eniyan wonyi ti a ti pe ki yoo towo ninu ase-ale ni (Luku 14:16-24).
EKO
Koni si awawi ti o le peye lati so fun Olorun lati gba elese ti ko ronupiwada lati wo orun rere. Olorun ti ran ipe re si gbogbo agbaye nipase omo re kan soso Jesu Kristi. Enikeni to ba gba Jesu Kristi gege bi Oluwa ati Olugbala re ni a o gba laye si orun rere, enikeni ti o ba si koo, ko ni le wo orun rere. Nitorina gbogbo wa ni lati mo pe Olorun ni agbara lati se ohunkohun ti o ba wuu ni okan re. gbogbo eniyan ni lati wariri niwaju Olorun ki a si gboran si ofin re. a ni lati se itewogba igbala Olorun ti ran si wa nipase Jesu Kristi ki a le wo orun rere.
ADURA
Olorun olufe, mo setan lati gba ipe igbala loni emi (Daruko re) fi aye mi fun Jesu Kristi. Mo gbaa ni Oluwa ati Olugbala mi, mo jewo ese mi, mo si ko won sile. Lati akoko yi lo, emi yi o sin o, un o si fi gbogbo eemi mi gbe o ga. Jowo je kin ye lati le wo ijoba re. ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
