LI ISOKAN NI A DURO
Kristeni ni lati mo pataki isokan, ki o si maa se papo bi okan. Bibeli ko wa ki a yera fun ipinya ati ijowu, ti o nse idiwo fun wiwasuu ihinrere. Ki Kristeni Kankan mase gbe ara re ga ju enikeji re, dipo bee, o ye ka sin Olorun pelu irele, ki a si ro ti enikeji saju tiwa. Bibeli wipe eni ti o ba nkiyesi ojo, o nkiyesi fun Oluwa, eni ti ko ba si kiyesi ojo, fun Oluwa ni ko kiyesii, Eniti njeun, o jeun fun Oluwa nitori o ndupe lowo Olorun, Eni ti ko ba si jeun, fun Oluwa ni ko jeun, o si ndupe lowo Olorun. Nitori ko si enikan ninu wa ti o wa laaye fun ara re, ko si si eni ti o nku fun ara re. Nitori bi a ba wa laaye, awa wa laaye fun Oluwa, bi a ba si ku awa ku fun Oluwa, nitori naa bi a wa laaye, tabi bi a ba ku, ti Oluwa ni awa ise. (Romu 14:6-8)
EKO
Isokan nmu itesiwaju ba Kristeni, sugbon ipinya yio je idena fun gbigboro. Satani ti tan Kristeni je nipa sise ifaga gbaga. Orisirisi ipinya Kristeni ni a nso wipe temi dara ju tire lo, a nle ohun ofo aye kiri, ti ko se iranlowo kankan fun ijoba Olorun. Olorun nfe ki awon omo re maa sin-in ninu iwa mimo, ati ni Emi Ominira lai faye gba ariyanjiyan ti o le Gegebi Romu 14:6-8 Olorun fi aye gba ijosin otito pelu Emi ominira, Bi enikeni ba di mo ofin Mose lati maa sin Olorun ni irele, ni gbangba, ninu otito, ki a si yera fun iwa wipe emi ni mo je olotito julo ti o le se ikuna fun gbigboro ihinrere.
ADURA
Olorun olufe, jowo gba awujo Kristeni lowo aisan ipinya. Je ki awon ara siwo ninu didara won lebi, ki a doju ko bi wiwasuu ihinrere yi o ti maa gbooro sii. Je ki eya Kristeni ni ifarada fun ara won ki won sise papo ni isokan, ki a baa le segun awon asodi si Kristeni. Jeki ijo ki o lo oro re ati agbara si awon ohun ti yio se okunfa, fun awon alaigbagbo lati di onigbagbo. Jowo, ro ara Kristi ni agbara ni gbogbo agbaye, ki a lee ma lepa ododo, ki oruko re lee gba iyin ni ile alaaye. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
