O KO LE YI OLORUN PADA
Inu Olorun ko dun si awon omo re ti nse aigboran, o ran wooli re lati kede idajo ti o nbo sori won. Olorun so fun wooli Hosea wipe fi ipe si enu re, Yio wa bi idi si ile Oluwa, nitori nwon ti re majemu mi koja, won si ti ru ofin mi. Won o kigbe simi pe, Olorun mi, awa Israeli mo o. Israeli ti gbe ohun rere sonu, ota yio lepa re. (Hosia 8:1-3).
EKO
Awon ti o ba lero wipe won le tan Olorun pelu iwa agabagebe, won ntan ara won je ni, nitori ko si enikeni ti o Lee se arumoloju fun Olorun. Olorun ni awon ofin ti ko see yipada. Gbogbo eniyan nilati fara mo gbigbe aye iwa mimo ki a lee di eni ibukun. Enikeni ti o ba ko lati gboran si ase Olorun, yio gba Idajo Olorun ni ojo ikehin. Nitori naa, ki gbogbo eniyan jawo ninu ise ibi, ki a sin Olorun ninu iwa mimo, ki a le ri ebun iye ayeraye gba ni orun.
ADURA
Olorun olufe, jowo ran mi lowo lati beru re ki emi si fi otito huwa niwaju re, ki emi lee se rere jowo ka mi yse fun ibukun re ti orun. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
