IGBALA NWA NIPA IJEWO
Jesu Kristi salaye wipe ilekun ijoba re ko ni je sisi fun gbogbo enikeni ti o ba ni oun un je Kristieni. Olugbala salaye wipe kii se gbogbo eni ti o ba pee ni Oluwa ni a o fun laye lati wo orun rere, ayafi awon ti o ba bori ire ije Kristieni won. Jesu wipe ‘E lakaka lati wo oju-ona tooro, nitori mo wi fun yin, eniyan pupo ni yoo wa ona ati wo o, won ki yo si le wole. Nigba ti bale ile ba dide leekan fuu ti o ba si ti se ilekun, eyin o si bere si duro lode, ti e o maa kankun wipe Oluwa Oluwa sii fun wa, oun o si dahun wi fun yin pe, emi ko mo ibi tie yin gbe ti wa. Nigba naa ni eyin o beere si wi pe, awa ti je, awa si ti mu niwaju re, iwo ni koni ni igboro ilu wa, oun o si wipe, emi wi fun yin, emi ko mo ibi tie yin gbe ti wa, e lo kuro lodo mi gbogbo eyin ti nsise ese. Ekun ati ipahinkeke yoo wa nibe, nigba ti eyin o ri Abrahaamu, ati Isaaki, ati Jakobu ati gbogbo awon wolii ni ijoba Olorun, ti a o si ti yin sode. Won o si ti ila-orun ati iwo-orun wa, ati lati ariwa, ati gusu wa, won a si jokoo ni ijoba Olorun. Si woo, awon eni-ehin nbe ti yoo di eni-iwaju, awon eni-iwaju nbe, ti yoo di eni-ehin.
(Luku 13:24-30).
EKO
Igbala rorun lati salaye ‘O je ona abayo ti Jesu Kristi pese (pelu emi ati aye re) ki elese le bo ninu ijiya ina orun apadi. Eniyan le di eni igbala, nigba ti o ba jewo Jesu Kristi ni Oluwa ati Olugbala re. o ye ki o ye wape, nini igbala je yiyan fun ara eni, a ko le jogun re, a ko si le ri gba fun elomiran. Onikuluku ni lati jewo Jesu Kristi ki o si gbaa ni Oluwa ki a to gba iru eni be sinu ijoba Olorun. O seese ki eniyan maa lo sile ijosin deede lai di eni igbala. Ko si eni ti o le di eni igbala nipa ise ijosin, olukuluku nilati jewo igbagbo re ninu Jesu Kristi ki o to le di eni igbala.
ADURA
Oluwa olufe mo gbagbo pe Jesu Kristi je omo re kan soso ti o ran lati orun, ti o gba eniyan la kuro ninu ijiya orun ina apadi. Mo jewo igbagbo mi ninu re, mo jewo pe Kristi ku fun ese mi, o si ji dide nipo oku lati fun mi ni iye ayeraye. Nidi eyi, mo gbaa ni Oluwa ati Olugbala, mo jewo ese mi, mo si ko won sile. Mo gbagbo pe mo di atunbi Kristieni, mo seleri lotito lati maa sin Olorun fun iyoku igbe aye mi. Amin.
