IFE TI KRISTI
Jesu Kristi sunkun, nitori o ri ebi ti won undekun lori iku Lasaru, Bibeli ko ni gbangba pe ‘JESU SUNKUN’ (John 11:35).
EKO
Jesu Kristi ni ife ti o jinle ati aajo fun awon omo ehin re, ko si ni ko won sile ni akoko isoro won. Awa kristieni je olori-ire, nitori Kristi yi o wa pelu wa ni gbogbo irin ajo aye wa, yi o si pin ninu irora wa. Olugbala yi o yi awon ohun ti o buru patapata pada si ibukun fun wa, omo Olorun ko ni simi titi yi o fi fun wa ni isegun lori ogun aye gbogbo, je ki onigbagbo ke ‘Halleluyah’
ADURA
Jesu Kristi olufe, iru olugbala iyanu wo ni o? o kii sun beni o ki togbe, o unso mi ni gbogbo akoko, mo feran re pupo pupo. Niwon bi o ti je olufokan tan ati abo mi, emi yi o tele o ni gbogbo aye mi, mo yonda gbogbo aye mi fun o titi lae. Emi yi o si so fun gbogbo aye pe iwo ni olugbala araye, ati ki gbogbo eniyan maa tele o. amin.
