IDABOBO OLORUN TITILAI NI
Abrahamu beru aye re, o ni ki Sara iyawo re so wipe oun je arabinrin re lati tan Abimeleki oba je okunrin naa lero pe awon eniyan Abemeleki yi o gba iyawo re, won o si pa oun. Abrahamu ti o ro wipe oun gbon lati puro bi oun ti je, o kuna lati mo pe Olorun lee se idabobo oun ninu ewu gbogbo. Itan Abrahamu lati fi pamo iru eni ti o je ni a koope ‘Abrahamu si wi niti Sara aya re pe, Arabinrin mi ni, Abimeleki Oba Gerari si ranse, o si mu Sara sugbon Olorun to Abimeleki wa ni oju iran ni oru, o si wi fun un pe, kiyesii, oku ni iwo, nitori obinrin ti iwo mu nni, nitori aya okunrin kan nii se. Sugbon Abimeleki ko sunmo on, o si wipe, Oluwa iwo o run orile ede olododo pelu. Oun ko lo ha wi fun mi pe arabinrin mi nii se? Oun, obinrin funra re si wi pe arakunrin mi ni, ni otito inu ati alaise owo mi, ni mo fi se eyi. Olorun si wi fun un ni ojura pe, bee ni emi mo pe ni otito inu re ni iwo se eyi, nitori naa ni emi si se da o duro ki o ma baa se mi, nitorinaa ni emi ko se je ki iwo ki o fowokan an. Nje nitori naa, mu aya okunrin naa pada fun un, wooli ni oun sa ise, oun o si gbadura fun o, iwo o si ye, bi iwo ko ba si mu un pada, ki iwo ki o mo pe kuku ni iwo o ku, iwo ati gbogbo eni ti o je tire. (Genesis 20:2-7).
EKO
Kristeni ni lati mo daju pe Olorun lee se alabo wa lowo awon ota wa. Bi o ti wu ki o ri, Olorun yi o se alabo wa, yi o si se ara re logo. Nitori naa, dipo ki onigbagbo faye gba iyemiji tabi wa ona aiwa bi Olorun, o ye ki o duro ninu igbagbo. Oye ki o ran ara re leti awon ileri ti a ko sinu bibeli lati ran igbagbo re lowo. Bibeli wipe nnkan wonyi ni mo ti so fun yin tele, ki eyin ki o le ni Alafia ninu mi, ninu aye, eyin o ni iponju sugbon e tujuka mo ti segun aye. (Johanu 16:33).
Olorun lee pese fun aini awon omo re. Yi o gba wa la ni igba ewu tabi isoro. Ni onakona ati igbakugba boya asise wa lati owo wa tabi lati odo elomiran Olorun yi o si maa je Olorun, yi o gbeja awon eniyan re lati yin ara re logo. Onigbagbo nilati ni igbekele ninu Oluwa. Ki a ni aseyori igbagbo pelu ireti. Isegun Olorun daju lori wa, niwon bi Jesu Kristi okan ni ni ana, ati ni oni, ati titi lae. (Heberu 13:8)
ADURA
Olorun olufe, jowo ko mi lati gbeke le o ni akoko isoro. Ran mi lowo lati gbeke le o ni igba gbogbo. Fi kun igbagbo mi, ki emi lee maa se ikewo igbagbo mi ni akoko isoro. Fun mi ni okun lati lee wipe mo mo Olorun ti mo nsin, yi o si gba mi lowo kiniun ati gbogbo Goliati aye. Jowo yi isoro aye mi di eri, ki awon alaigbagbo gbo ki won si wariri. Mu igbagbo mi duro, ki emi ki o lee tesiwaju ninu jijeri didara re ni ile alaaye. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere Amin.
