IBASEPO NINU IFE OLORUN
Iwa buburu je eewo si Olorun, yio si fiya je won. Elese kan ko ni lo lai jiya, ayafi ti o ba ronupiwada. Bibeli salaye eniyan ika” o fara pamo ni ibi kinniun ninu panti, o fara pamo lati mu talaka; a si mu talaka, nigba ti o ba faa sinu awon re. O ba, o re ara re sile, ki talaka ki o le bo si owo agbara re. O ti wi ni okan re pe Olorun ti gbagbe, o pa oju re mo, oun ki yoo ri laelae (Orin Dafidi 10:9-11)
EKO
Esan yio ke lori awon ika eniyan, afi ki won ronupiwada. Olorun yio won osuwon won yio si san won lesan bo ti to. Niwon igba ti Eledaa je alagbara idajo re lori onise buburu le ga pupo. Nitorina a nro gbogbo eniyan ki a ni iberu Olorun, ki a si se idajo pelu otito. Jehofa yio bukun awon eniyan ti won ba wa ni ibasepo didara pelu awon elomiran ki won si wa ninu ife.
ADURA
Olorun Olufe, emi ko fe je ika eniyan, jowo je ki emi je olooto ki emi si sooto si awon ara mi. Je ki emi lo gbogbo anfani ti mo ba ni lati bukun awon miran, ki a si gbe oruko re ga. Je ki Emi Mimo ro mi ni agbara lati je olotito omo re ni gbogbo ojo aye mi. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
