AWON ONIGBAGBO YIO GBA ERE WON NI ORUN
Paulu ati Sila ko si wahala nitori pe won waasu ihinrere ni Filippi Awon ara Filippi mu won, won si fiya je won lai ye won wo labe ofin. Won de won pelu ewon, won si so won sinu tubu. Sugbon awon mejeeji yi duro ninu igbagbo won. Won nyin Olorun ninu ipo to buru ti won wa yi, ohun iyanu nla si sele lesekese. Bibeli wipe sugbon laarin oganjo Paulu ati Sila ngbadura won si nkorin iyin si Olorun awon ara tuubu si nteti si won. Lojiji isele nla sise, tobee ti ipile tuubu mi titi, logan gbogbo ilekun si si, ide gbogbo won sit u sile. (Ise Awon Aposteli 16:25-26) Isele yi mu ki Oga oluso agba ewon ki o fi aye re fun Jesu Kristi.
EKO
Inunibini ko lee pa ina ihinrere, awon asodi si ihinrere le gbiyanju lati se inunibini si Kristeni, sugbon won ko lee bori. Awon omo Olorun kii se eniyan lasan, a fun won ni ore-ofe ati agbara lati orun wa, lati sise gidi, won si nsise takuntakun fun ijoba Olorun. Emi Mimo nro onigbagbo ni agbara lati le bori idojuko. Niwon ti a ti fun Kristeni ni agbara ko ye ki a beru enikeni. Kiki ki won mu okan le ninu ijewo Jesu Kristi, ki a si duro titi dopin. Bi o ti wu ki aye buru to, Jesu Kristi ti se ileri isegun fun awon Kristeni. Olugbala wipe nkan wonyi ni mo ti so fun yin tele, ki eyin ki o le ni Alafia ninu mi, ninu aye, eyin o ni iponju, sugbon e tujuka mo ti segun aye (Johanu 16:33)
ADURA
Olorun Olufe, jowo fun mi ni ore-ofe lati duro ninu igbagbo, je ki Emi Mimo re ro mi ni agbara, lati le duro sinsin lati le bori isoro ati idanwo gbogbo. Je ki emi maa korin isegun, mase je ki eri re kuro ni enu mi. Lehin irin ajo mi ninu aye yi, je ki ngbo ohun ti orun wipe kaabo osise Olotito. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.