FI IGBEKELE SINU AGBARA ABO OLORUN
Olorun damu oba saulu, ko je ki o segun Dafidi. Bibeli wipe, sauli si nrin ni apakan oke kan, Dafidi ati awon omokunrin re ni apa keji oke naa; Dafidi si yara lati sa kuro niwaju saulu nitoripe saulu ati awon omokunrin re ti rogba yi Dafidi ati awon omokunrin re ka lati mu won. Sugbon onise kan si to saulu wa, o si wipe, iwo yara ki o si wa nitori ti awon filistini ti gbe ogun ti ile wa. Saulu si pada kuro ni lilepa Dafidi, o si lo pade awon filistini; nitori naa ni won si se npe ibe naa ni selahamelekoti (ni itumo re, okuta ipinya). Dafidi ti goke lati ibe lo, o si jokoonibi ti o sapamo si ni engedi. (1Samueli 23: 26-29).
EKO
Olorun mo bi yoo se dabo bo awon omo re nigba ewu ati bi yio se damu awon ota won. Jehofa yi o gbo igbe awon omo re nigba kii gba ti won ba ke pee, yio si ja fun won. Bi omo olorun ba tile ja kule, Olorun a si saanu fun. Yio mu apadasehin omo wa sipo, ki satani ma baa yo won. Nitorina, gbogbo omo olorun ni lati sa si abe abo olorun ki won si gbeke won le agbara nla re ti enikeni ko le segun.
ADURA
Olorun olufe, mo gbagbo pe eyin ni o ni agbara julo ninu ohunalaaye, o si ni agbara lori ohun gbogbo. Mo wa be o ki o ran mi lowo lati segun gbogbo isoro. Jowo damu awon ota mi, ki won si subu sinu ise ibi won. Fun mi ni ibori lori awon aninilara mi, ki nsi gba aseyori lori won. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
