SO AHON RE, SO ORO ENU RE
O je ese ki a se ojusaju si eniyan. Olorun nfe ki awon omo re yera fun eleya meya, ki a si se bakan naa si gbogbo eniyan, Bibeli wipe ‘sugbon bi eyin ba nmu Olu ofin ni se gege bi iwe mimo, eyin ni, iwo fe enikeji re bi ara re, eyin nse daradara. Sugbon bi eyin ba nse ojusaaju eniyan, eyin ndese a si nda yin lebi nipa ofin bi arufin. (Jakobu 2:8-9)
EKO
Olojusaaju eniyan je alai sooto, Olorun ko ni foju foo ninu idajo re. Awon omo Olorun ni lati feran gbogbo eniyan ki a si huwa si won bakan naa. A ko gbudo sore fun oloro fun idaloro talaka. Enikeni ko ni lati bowo fun oloro, kii a si doju ti talaka. Olorun da gbogbo eniyan, a si je bakanaa niwaju re. O ro ojo re si gbogbo ori ile ati si eniyan lai si ojusaaju. Awon omo re ki o mase se ojusaaju bakannaa. Enikeni, ibaje Kristeni tabi alaigbagbo ti o ba nhuwa ipinya yi o jiya lati odo Olorun.
ADURA
Olorun Olufe, jowo ran mi lowo kin le se bakan naa si gbogbo eniyan. Mase je ki ntoju enikan ju enikeji lo, sugbon je ki se si won bakan naa pelu ife. Je ki nfi iberu Olorun se ohunkohun ti mo ba nse ki nba le ri ibukun re gba, laise eegun. Se mi ni ona ibukun fun gbogbo eniyan, ki oruko re le di yinyin ni igba gbogbo. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.