AYE ATI ORUN TI ISISINYI YIO RE KOJA
Olorun fihan Woli Danieli opin aye ti a daju. Aye yi yio pare, gbogbo eniyan buburu ti o ti gbe ninu re yio lo sinu orun ina apadi fun ijiya ayeraye. Bakannaa gbogbo awon ti won huwa bi Olorun nile aye yi yio gba ere iye ainipekun. Danieli salaye iran Olorun o ni ‘Ni akoko naa ni Mikaeli, balogun nla nni, ti yio gbeja awon Omo awon eniyan re yio dide, akoko wahala yio si wa, iru eyi ti ko tii si ri, lati igba ti orile-ede ti wa titi fi di igba akoko yii, ati ni igba akoko naa ni a gba awon eniyan re la, ani gbogbo awon ti a ti ko oruko won sinu iwe. Ati opolopo ninu awon ti o sun ninu erupe ile ni yioji, awon miran si iye ainipekun, ati awon miran si itiju ati egan ainipekun. Awon ologbon yio si maa tan bi imole ofurufu, awon ti o si nyi opolopo pada si ododo yio si maa tan bi irawo lae ati laelae. (Daniel 12:1-3)
EKO
Aye yi ati orun yio di ohun igbagbe, Olorun yio mu won wa si opin. Jehofa yio pa aye yi run ati gbogbo eda buburu ti won ti gbe ninu re ri. (Orun ti o wa bayi, a o muu kuro) Eledaa yio wa da aye ati orun titun nibi ti otito yio se ijoba. Gbogbo eniyan ti won ti gbe ninu aye yi, ti won si igbagbo pe Jesu Kristi je omo Olorun yio gbe ninu aye titun (ati ni orun titun) Jehofa yio pese alafia ayeraye fun aye ati orun titun, gbogbo awon eniyan mimo yoo ni itelorun ayeraye. Niwon igba ti aye yi yoo parun nikehin gbogbo eniyan ni lati lepa, ki won lee je alabapin ninu eyi titun ti nbo. Gbogbo okan nile aye ni lati gba Jesu Kristi gege bi omo Olorun tooto, ki won si jewo re bi Oluwa ati Olugbala won.
ADURA
Olorun Olufe jowo ka mi ye lati le jogun ainipekun re. Dari ese mi ji mi ki o si we mimo kuro ninu aisododo mi. Mo jewo Jesu Kristi, mo si gbaa bi Oluwa ati Olugbala mi. Jowo ko oruko mi sinu iwe iye, si ka mi ye fun aye titun ati orun titun ti nbo. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere, Amin.
